Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 3:34-42 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

34. Iye gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọ́n jẹ́ oṣù kan ó lé, èyí tí wọ́n kà jẹ́ igba mọ́kànlélọ́gbọ̀n (6,200).

35. Olórí àwọn ìdílé ìran Mérárì ni Súríélì ọmọ Ábíháílì, wọn yóò pa ibùdó wọn sí ìhà àríwá àgọ́.

36. Àwọn ìran Mérárì ni a yàn fún títọ́jú àwọn férémù àgọ́, ọ̀pá ìdábú rẹ̀, òpó rẹ̀, ihò òpó rẹ̀ àti gbogbo ohun èlò tó jẹ mọ́ lílò wọn;

37. Iṣẹ́ wọn tún ni títọ́jú àwọn òpó tó yí àgbàlá ká, ihò òpó rẹ̀, èèkàn àti okùn wọn.

38. Mósè àti Árónì pẹ̀lú àwọn ọmọ yóò pa àgọ́ ní ìdojúkọ ìwọ̀ oòrùn níwájú Àgọ́ Ìpàdé. Iṣẹ́ wọn ni láti máa mójútó iṣẹ́ ìsìn ibi mímọ́ àti láti máa ṣiṣẹ́ ìsìn fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Ẹnikẹ́ni tó bá súnmọ́ ibi mímọ́ yàtọ̀ sí àwọn tí a yàn, pípa ni kí ẹ pa á.

39. Àpapọ̀ iye àwọn ọmọ Léfì tí a kà gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pa á láṣẹ fún Mósè àti Árónì gẹ́gẹ́ bí ìran wọn, pẹ̀lú gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ọmọ oṣù kan ó lé jẹ́ ẹgbàá mọ́kànlá (22,000).

40. Olúwa sọ fún Mósè pé, “Ka gbogbo àkọ́bí ọmọkùnrin Ísírẹ́lì láti ọmọ oṣù kan ó lé kí o sì ṣe àkọsílẹ̀ orúkọ wọn.

41. Kí o sì gba àwọn ọmọ Léfì dípò gbogbo àkọ́bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, kí o sì gba gbogbo ẹran ọ̀sìn àwọn ọmọ Léfì fún mi dípò gbogbo àkọ́bí àwọn ẹran ọ̀sìn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Èmi ni Olúwa.”

42. Mósè sì ka gbogbo àkọ́bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún un.

Ka pipe ipin Nọ́ḿbà 3