Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 22:13-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

13. Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì Bálámù dìde ó sì sọ fún àwọn ìjòyè Bálákì pé, “Ẹ padà sí orílẹ̀ èdè yín, nítorí tí Olúwa ti kọ̀ láti jẹ́ kí n tẹ̀lé yín.”

14. Nígbà náà àwọn ìjòyè Móábù sì padà tọ Bálákì lọ wọ́n sì wí pé, “Bálámù kọ̀ láti tẹ̀lé wa.”

15. Nígbà náà Bálákì rán àwọn ìjòyè mìíràn tí wọ́n pọ̀ àwọn tí wọ́n sì níyì ju alákọ́kọ́ lọ.

16. Wọ́n lọ sí ọ̀dọ̀ Bálámù wọ́n sì sọ pé:“Èyí ni ohun tí Bálákì ọmọ Sípórì sọ: Má ṣe jẹ́ kí ohunkóhun kí ó dè ọ́ lọ́nà láti wá sí ọ̀dọ̀ mi,

17. Nítorí pé èmi yóò fún ọ ní ẹ̀bùn dáradára màá sì ṣe ohunkóhun tí o bá sọ. Wá kí o sì wá fi àwọn ènìyàn wọ̀nyí bú fún mi.”

18. Ṣùgbọ́n Bálámù dá wọn lóhùn pé, “Kó dà tí Bálákì bá fún mi ní ààfin rẹ̀ tí ó kún fún fàdákà àti wúrà, n kò ṣe ohunkóhun tí ó tóbi tàbí kéré tí o kọjá òfin Olúwa Ọlọ́run mi.

19. Nísinsìnyìí ẹ dúró níbí di ọjọ́ kejì gẹ́gẹ́ bí àwọn tókù ti ṣe nígbà náà èmi yóò mọ ohun tí Olúwa yóò tún sọ fún mi.”

20. Ní alẹ́ ọjọ́ náà Ọlọ́run sì tọ Bálámù wá ó sì sọ wí pé, “Nígbà tí ọkùnrin yìí ti wá pè ọ́, lọ pẹ̀lú wọn, ṣùgbọ́n ẹnu nǹkan tí mo sọ fún ọ ni kí o ṣe.”

21. Bálámù dìde ní òwúrọ̀, ó sì di ẹrù lé kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ òun pẹ̀lú àwọn ìjòyè Móábù.

22. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run bínú gidigidi, áńgẹ́lì Olúwa sì dúró lójú ọ̀nà láti dojú ìjà kọ ọ́. Bálámù ń gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ lọ, àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ méjì sì wà pẹ̀lú rẹ̀.

23. Nígbà tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà sì rí áńgẹ́lì Olúwa tí ó dúró ní ojú ọ̀nà pẹ̀lú idà tí a fà yọ ní ọwọ́ rẹ̀, ó kọjú kúrò ní ọ̀nà lọ sínú oko. Bálámù sì lù ú pé kí ó gbé òhun padà lọ sí ojú ọ̀nà.

24. Nígbà náà ángẹ́lì Olúwa dúró ní ojú ọ̀nà tóóró láàrin ọgbà àjàrà, pẹ̀lú ògiri ní ọ̀nà méjèèjì.

25. Nígbà tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rí ángẹ́lì Olúwa, ó lẹ̀ mọ́ ẹ̀gbẹ́ ògiri, ó sì rún ẹsẹ̀ Bálámù mọ́ ògiri. Nígbà náà, ó tún nàá, lẹ́ẹ̀kan sí i.

26. Nígbà náà ángẹ́lì Olúwa súnmọ́ wájú ó sì dúró níbi ọ̀nà tóóró níbi tí kò ti sí ọ̀nà láti yípadà, bóyá ní ọ̀tún tàbí òsì.

27. Nígbà tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rí ángẹ́lì Olúwa, ó sì jókó ní abẹ́ Bálámù, inú sì bí i tó sì ná-àn pẹ̀lú ọ̀pá rẹ̀.

28. Nígbà náà Olúwa sí ẹnu kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ó sì sọ fún Bálámù pé, “Kí ni mo ṣe fún ọ tí o fi nà mí lẹ́ẹ̀mẹ́ta?”

Ka pipe ipin Nọ́ḿbà 22