Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 20:9-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Báyìí ni Mósè mú ọ̀pá láti iwájú Olúwa wá, gẹ́gẹ́ bí ó ti paláṣẹ fún un.

10. Òun àti Árónì pe àwọn ènìyàn jọ sí ojú kan níwájú àpáta, Mósè sì sọ fún wọn, “Ẹ gbọ́, ẹ̀yín ọlọ̀tẹ̀, àwa kì yóò lè mú omi jáde láti inú àpáta yìí wá bí?”

11. Nígbà náà ni Mósè gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè ó sì fi ọ̀pá ọwọ́ rẹ̀ lu àpáta lẹ́ẹ̀méjì. Omi sì tú jáde, gbogbo ìjọ ènìyàn àti àwọn ẹran ọ̀sìn wọn sì mu.

12. Ṣùgbọ́n Olúwa sọ fún Mósè àti Árónì pé, “Nítorí pé ẹ̀yin kò gbà mí gbọ́ tó láti bu ọlá fún mi níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ìwọ kò ní kó àwọn ìjọ ènìyàn yìí dé ilẹ̀ tí mo fún wọn.”

13. Èyí ni omi ti Méríbà, níbi tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti bá Olúwa jà àti ibi tí O ti fi ara rẹ̀ hàn bí ẹni mímọ́ láàrin wọn.

14. Mósè sì ránṣẹ́ láti Kádésì sí ọba Édómù, wí pé:“Èyí ni nǹkan tí arákùnrin rẹ Ísírẹ́lì sọ: Ìwọ ti mọ̀ nípa gbogbo ìnira, tí ó wá sí orí wa.

15. Àwọn bàbá ńlá wa sọ̀kalẹ̀ wá sí Éjíbítì, a sì gbé ibẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ọdún. Àwọn ará Éjíbítì ni wá lára àti àwọn bàbá wa,

16. ṣùgbọ́n nígbà tí a sunkún sí Olúwa, ó gbọ́ ẹkún wa, ó sì rán ańgẹ́lì kan sí wa, ó sì mú wa jáde láti Éjíbítì.“Báyìí àwa wà ní Kádésì, ìlú tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ ilẹ̀ rẹ.

17. Jọ̀wọ́ jẹ́ kí a gba orílẹ̀ èdè rẹ kọjá, Àwa kì yóò gba inú oko tàbí ọgbà àjàrà rẹ kọjá, tàbí mu omi láti inú kàǹga. A ó ma kọjá ní òpópónà ọba, àwa kì yóò yà sí ọ̀tún tàbí sí òsì títí àwa yóò fi kọjá ní ilẹ̀ rẹ.”

18. Ṣùgbọ́n Édómù dáhùn pé:“Ẹ̀yin kò le gba ibí kọjá; bí ẹ bá dán an wò, a ó dìde ogun síyín a ó sì bá yín jà pẹ̀lú idà.”

19. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dáhùn pé:“A ó gba ọ̀nà tóóró, bí àwa tàbí ẹran ọ̀sìn wa bá sì mú lára omi rẹ, a ó san owó rẹ̀. A kàn fẹ́ rìn kọjá lórí ilẹ̀ rẹ ni kò sí nǹkankan mìíràn tí a fẹ́ ṣe.”

20. Wọ́n tún dáhùn wí pé:“Ẹ kò lè kọjá.”Nígbà náà ni Édómù jáde wá láti kọjú ìjà sí wọn pẹ̀lú ọ̀pọ̀ àti alágbára ọmọ ogun.

21. Nígbà tí Édómù sì kọ̀ jálẹ̀ láti jẹ́ kí wọn kọjá ní ilẹ̀ wọn, Ísírẹ́lì yípadà kúrò lọ́dọ̀ wọn.

22. Gbogbo ìjọ ènìyàn Ísírẹ́lì sì jáde láti Kádésì wọ́n sì wá sí orí òkè Hórì.

23. Ní orí òkè Hórì, ní ẹ̀gbẹ́ ààlà Édómù Olúwa sọ fún Mósè àti Árónì pé,

24. “Árónì yóò kú. Kò ní wọ ilẹ̀ tí mo fi fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, nítorí ẹ̀yin méjèèjì ṣe àìgbọ́ràn sí òfin mi níbi omi Méríbà.

Ka pipe ipin Nọ́ḿbà 20