Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 20:17-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

17. Jọ̀wọ́ jẹ́ kí a gba orílẹ̀ èdè rẹ kọjá, Àwa kì yóò gba inú oko tàbí ọgbà àjàrà rẹ kọjá, tàbí mu omi láti inú kàǹga. A ó ma kọjá ní òpópónà ọba, àwa kì yóò yà sí ọ̀tún tàbí sí òsì títí àwa yóò fi kọjá ní ilẹ̀ rẹ.”

18. Ṣùgbọ́n Édómù dáhùn pé:“Ẹ̀yin kò le gba ibí kọjá; bí ẹ bá dán an wò, a ó dìde ogun síyín a ó sì bá yín jà pẹ̀lú idà.”

19. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dáhùn pé:“A ó gba ọ̀nà tóóró, bí àwa tàbí ẹran ọ̀sìn wa bá sì mú lára omi rẹ, a ó san owó rẹ̀. A kàn fẹ́ rìn kọjá lórí ilẹ̀ rẹ ni kò sí nǹkankan mìíràn tí a fẹ́ ṣe.”

20. Wọ́n tún dáhùn wí pé:“Ẹ kò lè kọjá.”Nígbà náà ni Édómù jáde wá láti kọjú ìjà sí wọn pẹ̀lú ọ̀pọ̀ àti alágbára ọmọ ogun.

21. Nígbà tí Édómù sì kọ̀ jálẹ̀ láti jẹ́ kí wọn kọjá ní ilẹ̀ wọn, Ísírẹ́lì yípadà kúrò lọ́dọ̀ wọn.

22. Gbogbo ìjọ ènìyàn Ísírẹ́lì sì jáde láti Kádésì wọ́n sì wá sí orí òkè Hórì.

23. Ní orí òkè Hórì, ní ẹ̀gbẹ́ ààlà Édómù Olúwa sọ fún Mósè àti Árónì pé,

24. “Árónì yóò kú. Kò ní wọ ilẹ̀ tí mo fi fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, nítorí ẹ̀yin méjèèjì ṣe àìgbọ́ràn sí òfin mi níbi omi Méríbà.

25. Mú Árónì àti ọmọ rẹ̀ Élíásárì lọ sí orí òkè Hórì.

26. Bọ́ aṣọ Árónì kí o sì gbe wọ ọmọ rẹ̀ Élíásárì, nítorí pé Árónì yóò kú ṣíbẹ̀.”

27. Mósè sì ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pa láṣẹ: Wọ́n lọ sí orí òkè Hórì ní ojú gbogbo ìjọ ènìyàn.

28. Mósè bọ́ aṣọ Árónì ó sì gbe wọ ọmọ rẹ̀ Élíásárì, Árónì sì kú sí orí òkè. Nígbà náà Mósè àti Élíásárì sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè,

29. Nígbà tí gbogbo ìjọ ènìyàn sì gbọ́ pé Árónì ti kú, gbogbo ilé Ísírẹ́lì ṣe ìdárò rẹ̀ fún ọgbọ̀n (30) ọjọ́.

Ka pipe ipin Nọ́ḿbà 20