Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 16:36-50 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

36. Olúwa sọ fún Mósè pé,

37. “Sọ fún Élíásárì ọmọ Árónì tí í ṣe àlùfáà, pé kí ó mú àwọn àwo tùràrí jáde kúrò nínú iná nítorí pé wọ́n jẹ́ mímọ́, kí ó sì tan iná náà káàkiri síbi tó jìnnà.

38. Èyí ni àwo tùràrí àwọn tí ó kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Kí ẹ gún àwo tùràrí yìí, kí ẹ sì fi ṣe ìbòrí fún pẹpẹ, wọ́n jẹ́ mímọ́ nítorí pé wọ́n ti mú wọn wá ṣíwájú Olúwa. Kí wọ́n jẹ́ àmì fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.”

39. Élíásárì tí í ṣe àlùfáà sì kó gbogbo àwo tùràrí tí àwọn tí ó jóná mú wa, ó gún wọn pọ̀, ó fi ṣe ìbòrí fún pẹpẹ,

40. Gẹ́gẹ́ bí Olúwa ṣe sọ láti ẹnu Mósè. Èyí yóò jẹ́ ohun ìrántí fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ẹlòmíràn yàtọ̀ sí irú ọmọ Árónì kò gbọdọ̀ jó tùràrí níwájú Olúwa, ẹni tí ó bá ṣe bẹ́ẹ̀, yóò dàbí Kórà àti àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀.

41. Ní ọjọ́ kejì gbogbo ìjọ ènìyàn kùn sí Mósè àti Árónì pé, “Ẹ ti pa àwọn ènìyàn Olúwa.”

42. Ṣùgbọ́n nígbà tí gbogbo ìjọ ènìyàn péjọ lòdì sí Mósè àti Árónì, níwájú àgọ́ ìpàdé, lójijì ni ìkúùkù bolẹ̀, ògo Olúwa sì fara hàn.

43. Nígbà náà ni Mósè àti Árónì lọ ṣíwájú àgọ́ ìpàdé,

44. Olúwa sì sọ fún Mósè pé,

45. “Yàgò kúrò láàrin ìjọ ènìyàn yìí, kí ń ba le run wọ́n ní ìṣẹ́jú kan.” Wọ́n sì dojú bolẹ̀.

46. Mósè sì sọ fún Árónì pé, “Mú àwo tùràrí, kí o fi iná sí i lórí pẹpẹ, fi tùràrí sínú rẹ̀, kí o sì tètè mu lọ sí àárin ìjọ ènìyàn láti ṣètùtù fún wọn nítorí pé ìbínú Olúwa ti jáde, àjàkálẹ̀-àrùn sì ti bẹ̀rẹ̀.”

47. Árónì ṣe bí Mósè ti wí, ó sáré lọ sí àárin àwọn ènìyàn, ṣùgbọ́n àjàkálẹ̀-àrùn ti bẹ̀rẹ̀ láàrin wọn, ṣùgbọ́n Árónì fín tùràrí, ó sì ṣe ètùtù fún wọn.

48. Ó dúró láàrin àwọn alààyè àti òkú, àjàkálẹ̀-àrùn náà sì dúró.

49. Ṣùgbọ́n àjàkálẹ̀-àrùn ti pa ẹgbàá méje ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin (14,700) ènìyàn ní àfikún sí àwọn tí ó kú níbi ìṣẹ̀lẹ̀ Kórà.

50. Árónì padà tọ Mósè lọ ní ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Ìpade nítorí pé àjàkálẹ̀-àrùn náà ti dúró.

Ka pipe ipin Nọ́ḿbà 16