Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 15:1-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Olúwa sọ fún Mósè pé;

2. “Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: ‘Nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ tí èmi ó fún yin gẹ́gẹ́ bí ibùgbé

3. tí ẹ sì mú ọrẹ àfinásun wá, yálà nínú ọ̀wọ́ ẹran gẹ́gẹ́ bí òórùn dídùn sí Olúwa, bóyá ọrẹ sísun tàbí ẹbọ sísun, láti san ẹ̀jẹ́ pàtàkì tàbí ọrẹ àtinúwá,

4. nígbà náà ni kí ẹni tí ó bá mú ọrẹ rẹ̀ wá, yóò tún mú ẹbọ ohun jíjẹ ìdámẹ́wàá òṣùwọ̀n ìyẹ̀fun kíkúná pẹ̀lú ìdásímẹ́rin òṣùwọ̀n òróró wá ṣíwájú Olúwa.

5. Pẹ̀lú ọ̀dọ́ àgùntàn kọ̀ọ̀kan yálà fún ọrẹ tabí ẹbọ sísun ni, kí ẹ pèsè ìdá sí mẹ́rin òṣùwọ̀n wáìnì gẹ́gẹ́ bí ohun mímu.

6. “ ‘Fún àgbò kan ni kí ẹ pèsè ọrẹ ohun jíjẹ ìdá méjì nínú mẹ́wàá òṣùwọ̀n ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi ìdá kan nínú mẹ́ta òṣùwọ̀n òróró pò.

7. Àti ìdá kan nínú mẹ́ta òṣùwọ̀n wáìnì fún ọrẹ ohun mímu gẹ́gẹ́ bí òórùn dídùn sí Olúwa.

8. “ ‘Nígbà tí ẹ bá sì pèsè ọ̀dọ́ akọ màlúù fún ọrẹ tàbí ẹbọ sísun, láti fi san ẹ̀jẹ́ tàbí fún ọrẹ àlàáfíà sí Olúwa,

9. Ẹni náà yóò mú ọ̀dọ́ akọ màlúù náà wá pẹ̀lú ọrẹ ohun jíjẹ, ìdá sí mẹ́ta nínú mẹ́wàá òṣùwọ̀n ìyẹ̀fun ìyẹ̀fun kíkúná tí a fi ìdajì òṣùwọ̀n òróro pò.

10. Kí ó tún mú ìdajì òsùwọ̀n wáìnì wá fún ọrẹ ohun mímu. Yóò jẹ́ ọrẹ àfinásun, àní òórùn dídùn sí Olúwa.

11. Báyìí ni kí ẹ se pèṣè ọ̀dọ́ akọ màlúù tàbí àgbò, ọ̀dọ́ àgùntàn tàbí ọmọ ewúrẹ́.

Ka pipe ipin Nọ́ḿbà 15