Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 1:34-44 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

34. Láti ìran Mánássè:Gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún sókè, tí wọ́n lè lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn.

35. Iye tí a kà nínú ẹ̀yà Mánásè jẹ́ ẹgbàá ẹ́rìndínlógún-ó-lé-igba (32,200).

36. Láti ìran Bẹ́ńjámínì:Gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún sókè ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn.

37. Iye tí a kà nínú ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì jẹ́ ẹgbàá mẹ́tadínlógún-ó-lé-egbéje (35,400).

38. Láti ìran Dánì:Gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ọmọ ogún ọdún sókè, tí wọ́n lè lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn.

39. Iye tí a kà nínú ẹ̀yà Dánì jẹ́ ẹgbàá mọ́kànlélọ́gbọ̀n-ó-lé-ẹẹ̀dẹ́gbẹ̀rin (62,700).

40. Láti ìran Ásérì:Gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún sókè, tí wọ́n le lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn.

41. Iye tí a kà nínú ẹ̀yà Áṣérì jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì-ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ (41,500).

42. Láti ìran Náfítalì:Gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún ó lé, tí wọ́n lè lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn.

43. Iye àwọn tí a kà nínú ẹ̀yà Náfítalì jẹ́ ẹgbàá mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n-ó-lé-egbéje (53,400).

44. Wọ̀nyí ni àwọn ènìyàn tí Mósè àti Árónì kà, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn olórí méjìlá (12) fún Ísírẹ́lì, tí ẹnìkọ̀ọ̀kan sojú fún ìdílé rẹ̀.

Ka pipe ipin Nọ́ḿbà 1