Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nehemáyà 4:10-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Lákòókò yìí, àwọn ènìyàn Júdà wí pé, “Agbára àwọn òṣìṣẹ́ ti dínkù, àlàpà púpọ̀ ni ó wà tó bẹ́ẹ̀ tí àwa kò fi le è mọ odi náà.”

11. Bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn ọ̀ta wa wí pé, “Kí wọn tó mọ̀ tàbí kí wọn tó rí wa, àwa yóò ti dé àárin wọn, a ó sì pa wọ́n, a ó sì dá iṣẹ́ náà dúró.”

12. Nígbà náà ni àwọn Júù tí ó ń gbé ní ẹ̀gbẹ́ẹ wọn wá sọ fún wa ní ìgbà mẹ́wàá pé, “Ibikíbi tí ẹ̀yin bá padà sí, wọn yóò kọ lù wá.”

Ka pipe ipin Nehemáyà 4