Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nehemáyà 4:1-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nígbà tí Ṣáńbálátì gbọ́ pé àwa ń tún odi náà mọ, ó bínú, ó sì bínú púpọ̀. Ó fi àwọn ará Júù ṣe ẹlẹ́yà,

2. ó sọ níwájú àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ àti níwájú àwọn ọmọ ogun Ṣamáríà pé, “Kí ni àwọn aláìlera Júù wọ̀nyí ń ṣe yìí? Ṣé wọn yóò mú odi wọn padà ni? Ṣé wọn yóò rú ẹbọ ni? Ṣé wọn yóò paríi rẹ̀ lóòjọ́ ni bí? Ṣé wọ́n lè mú òkúta tí a ti ṣun láti inú òkítì padà bọ̀ sípò tí ó jóná bí wọ́n ṣe wà yẹn?”

3. Tóbíyà ará Ámónì, ẹni tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀, wí pé, “Ohun tí wọ́n ń mọ—bí kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ lásán bá gùn-ún sókè, yóò fọ́ odi òkúta wọn lulẹ̀!”

4. Gbọ́ ti wa, Ọlọ́run wa, nítorí àwa di ẹni ẹ̀gàn. Dá ẹ̀gàn wọn padà sórí ara wọn. Kí o sì fi wọ́n fún ìkógun ní ilẹ̀ ìgbékùn.

5. Má ṣe bo ẹ̀bi wọn tàbí wẹ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn nù kúrò níwájúú rẹ, nítorí wọ́n mú ọ bínú níwájú àwọn ọ̀mọ̀lé.

6. Bẹ́ẹ̀ ni àwa mọ odi náà títí gbogbo rẹ̀ fi dé ìdajìi gíga rẹ̀, nítorí àwọn ènìyàn ṣiṣẹ́ pẹ̀lúu gbogbo ọkàn an wọn.

7. Ṣùgbọ́n nígbà tí Ṣáńbálátì, Tóbíyà, àwọn ará Árábù, ará Ámónì, àti àwọn ènìyàn Áṣídódì gbọ́ pé àtúnṣe odi Jérúsálẹ́mù ti ga dé òkè àti pé a ti mọ àwọn ibi tí ó yá dí, inú bí wọn gidigidi.

8. Gbogbo wọn jọ gbìmọ̀ pọ̀ láti wá bá Jérúsálẹ́mù jà àti láti dìde wàhálà sí í.

9. Ṣùgbọ́n àwa gbàdúrà sí Ọlọ́run wa, a sì yan olùṣọ́ ọ̀sán àti ti òru láti kojú ìhàlẹ̀ yìí.

10. Lákòókò yìí, àwọn ènìyàn Júdà wí pé, “Agbára àwọn òṣìṣẹ́ ti dínkù, àlàpà púpọ̀ ni ó wà tó bẹ́ẹ̀ tí àwa kò fi le è mọ odi náà.”

11. Bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn ọ̀ta wa wí pé, “Kí wọn tó mọ̀ tàbí kí wọn tó rí wa, àwa yóò ti dé àárin wọn, a ó sì pa wọ́n, a ó sì dá iṣẹ́ náà dúró.”

12. Nígbà náà ni àwọn Júù tí ó ń gbé ní ẹ̀gbẹ́ẹ wọn wá sọ fún wa ní ìgbà mẹ́wàá pé, “Ibikíbi tí ẹ̀yin bá padà sí, wọn yóò kọ lù wá.”

13. Nítorí náà mo dá ènìyàn díẹ̀ dúró níbi tí ó rẹlẹ̀ jù lẹ́yìn odi ní ibi gbangba, mo fi wọ́n síbẹ̀ nípa àwọn ìdílée wọn, pẹ̀lú àwọn idà wọn, àwọn ọ̀kọ̀ wọn àti àwọn ọrun wọn.

14. Lẹ́yìn ìgbà tí mo wo àwọn nǹkan yíká, mo dìde mo sì wí fún àwọn ọlọ́lá àwọn ìjòyè àti àwọn ènìyàn tó kù pé, “Ẹ má ṣe bẹ̀rù u wọn. Ẹ rántí Olúwa, ẹni tí ó tóbi, tí ó sì ní ẹ̀rù, kí ẹ sì jà fún àwọn arákùnrin yín, àwọn ọmọkùnrin yín, àwọn ọmọbìnrin yín, àwọn ìyàwó yín àti àwọn ilée yín.”

Ka pipe ipin Nehemáyà 4