Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nehemáyà 2:10-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Nígbà tí Ṣáńbálátì ará Hórónì àti Tòbáyà ará a Ámónì tí wọ́n jẹ́ ìjòyè gbọ́ nípa èyí pé, ẹnikan wá láti mú ìtẹ̀ṣíwájú bá àlàáfíà àwọn ará Ísírẹ́lì inú bí wọn gidigidi.

11. Mo sì lọ sí Jérúsálẹ́mù, lẹ́yìn ìgbà tí mo dúró níbẹ̀ fún ọjọ́ mẹ́ta.

12. Mo jáde ní òru pẹ̀lú àwọn ọkùnrin díẹ̀. Èmi kò sì sọ fún ẹnikankan ohun tí Ọlọ́run mi ti fi sí ọkàn mi láti ṣe fún Jérúsálẹ́mù. Kò sí ẹranko kankan pẹ̀lúu mi, bí kò ṣe ọ̀kan ṣoṣo tí mo gùn.

13. Ní òru, mo jáde lọ sí àfonífojì ibodè sí ìhà kànga Jákálì àti sí ẹnu ibodè jààtàn àti ẹnu ibodè rẹ̀ èyí tí ó ti wó lulẹ̀, tí a ti fi iná sun.

14. Nígbà náà ni mo lọ sí ẹnu ibodè oríṣun àti sí adágún omi ọba, ṣùgbọ́n kò sí ààyè tó fún ẹranko mi láti kọjá;

15. Bẹ́ẹ̀ ni mo gòkè àfonífojì ní òru, mo ń wo odi. Ní ìparí, mo padà ṣẹ́yìn, mo sì tún wọlé láti ibodè àfonífojì.

16. Àwọn olórí kò mọ ibi tí mo lọ tàbí mọ ohun tí mo ń ṣe, nítorí èmi kò tí ì sọ fún àwọn ará Júù tàbí àwọn àlùfáà tàbí àwọn ọlọ́lá tàbí àwọn ìjòyè tàbí ẹnikẹ́ni mìíràn tí yóò máa ṣe iṣẹ́ náà.

17. Nígbà náà ni mo sọ fún wọn pé, “Ṣé ẹ rí wàhálà tí a wọ̀: Jérúsálẹ́mù wà nínú ìparun, ibodè rẹ̀ ni a sì ti fi iná jó. Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a tún odi Jérúsálẹ́mù mọ, àwa kò sì ní jẹ́ ẹni ẹ̀gàn mọ́”

Ka pipe ipin Nehemáyà 2