Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nehemáyà 12:31-47 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

31. Mo sì tún yan àwọn olórí Júdà láti gun orí odi náà. Mo sì tún yan àwọn ẹgbẹ́ akọrin ńlá méjì láti dúpẹ́. Àwọn kan yóò gòkè odi lọ sí apá ọ̀tún sí ọ̀nà ibodè Ààtàn.

32. Hósáyà àti ìdajì àwọn olórí Júdà tẹ̀lé wọn,

33. Àwọn wọ̀nyí náà sì lọ pẹ̀lúu wọn, Áṣáráyà, Éṣírà, Mésúlámù,

34. Júdà, Bẹ́ńjámínì, Ṣémáyà, Jeremáyà,

35. Pẹ̀lú àwọn àlùfáà díẹ̀ pẹ̀lú ipè (kàkàkí), pẹ̀lúu Ṣakaráyà ọmọ Jónátanì, ọmọ Ṣémáyà, ọmọ Matanáyà, ọmọ Míkáyà, ọmọ Ṣákúrì, ọmọ Áṣáfì,

36. Àti àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ rẹ̀—Ṣémáyà, Áṣárélì, Míláláì, gíláláì, Mááì, Nétanélì, Júdà àti Hánánì—pẹ̀lú ohun èlò orin bí àṣẹ Dáfídì ènìyàn Ọlọ́run. Éṣírà akọ̀wé ni ó sáájúu wọn bí wọ́n ti ń tò lọ lọ́wọ̀ọ̀wọ́.

37. Ní ẹnu ibodè oríṣun wọ́n ti ń lọ tààrà sí ọ̀nà ní orí àtẹ̀gùn ìlú Dáfídì ní orí òkè tí ó kángun sí odi, wọ́n sì gba ẹ̀gbẹ́ ilée Dáfídì kọjá títí dé ẹnu ibodè omi ní ìhà ìlà oòrùn.

38. Àwọn ẹgbẹ́ akọrin kejì gba ọ̀nà òdì kejì lọ. Mo tẹ̀lé wọn ní orí odi, pẹ̀lú ìdajì àwọn ènìyàn, kọjá ilé ìṣọ́ ìléru lọ sí odi fífẹ̀,

39. Kọjá ẹnu ibodè Éúfúrẹ́mù ibodè Jéṣánà, ẹnu ibodè ẹja, ilé ìṣọ́ Hánánélì àti ilé ìṣọ́ ọgọ́rùn—ún, títí dé ẹnu ibodè àgùntàn. Wọ́n sì dúró ní ibodè ìṣọ́.

40. Àwọn ẹgbẹ́ akọrin méjèèjì tí wọ́n dúpẹ́ wà ní ààyè nínú ilé Ọlọ́run, èmi náà sì dúró ní ààyè mi pẹ̀lú ìdajì àwọn ìjòyè,

41. Àti àwọn àlùfáà—Élíákímù, Máṣéyà, Míníámínì, Míkáyà, Éliánáyì, Ṣaráyà àti Hananáyà pẹ̀lú àwọn ìpèe (kàkàkí) wọn.

42. Àti pẹ̀lú Maáṣéyà, Ṣémáyà, Éṣérì. Àwọn ẹgbẹ́ akọrin ní abẹ́ ìṣàkóso Jéṣíráyà.

43. Ní ọjọ́ náà wọ́n rú ẹbọ ńlá, wọ́n ṣe àjọyọ̀ nítorí Ọlọ́run ti fún wọn ní ayọ̀ ńlá. Àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé sì yọ̀ pẹ̀lú. A lè gbọ́ ariwo ayọ̀ tí ó jáde láti Jérúsálẹ́mù ní jìnnà réré.

44. Ní àkókò náà, a yan àwọn ènìyàn láti jẹ́ alábojútó yàrá ìkó ẹrù fún àwọn ọrẹ àkọ́so èso àti àwọn ìdámẹ́wàá. Láti inú àwọn oko tí ó wà ní àyíká ìlú ni wọ́n ti ní láti mú wá sínú yàrá ìkó nǹkan sí ìpín tí òfin sọ fún àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì, nítorí inú un àwọn ará a Júdà yọ́ sí àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ, Léfì tó ń ṣiṣẹ ìránṣẹ.

45. Wọ́n ń ṣiṣẹ́ Ọlọ́run wọn àti iṣẹ́ ìyàsímímọ́, bẹ́ẹ̀ náà ni fún àwọn akọrin àti àwọn aṣọ́nà, wọ́n ń ṣe gẹ́gẹ́ bí Dáfídì àti Sólómónì ọmọ rẹ̀ ti pa á láṣẹ fún wọn.

46. Ní ọjọ́ pípẹ́ ṣẹ́yìn ní ìgbà Dáfídì àti Áṣáfì, ni àwọn atọ́nisọ́nà, ti wà fún àwọn akọrin àti fún orin ìyìn àti orin ọpẹ́ sí Ọlọ́run.

47. Nítorí náà ní ìgbà ayé Ṣérúbábélì àti Nehemáyà, gbogbo Ísírẹ́lì ni ó ń dá ìpín lójoojúmọ́ fún àwọn akọrin àti àwọn aṣọ́nà. Wọ́n sì tún yan ìpín mìíràn ṣọ́tọ̀ fún àwọn ọmọ Léfì tó kù àwọn ọmọ Léfì náà tún ya ìpín ti àwọn ọmọ Árónì sọ́tọ̀ fún wọn.

Ka pipe ipin Nehemáyà 12