Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nehemáyà 12:21-33 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

21. ti ìdílé Hílíkíáyà, Háṣábíáyà;ti ìdílé Jédáíáyà, Nétanẹ́lì.

22. Àwọn olóórí ìdílé àwọn ọmọ Léfì ní ìgbà ayé Élíáṣíbù, Jóíádà, Jóhánánì àti Jádúà, àti pẹ̀lú ti àwọn àlùfáà ni a kọ sílẹ̀ ní ìgbà ìjọba Dáríúsì ará a Páṣíà.

23. Àwọn olórí ìdílé láàrin àwọn ọmọ Léfì títí di àkókò Jóhánánì ọmọ Élíáṣíbù ni a kọ sílẹ̀ nínú ìwé ìtàn.

24. Àti àwọn olóórí àwọn ọmọ Léfì ni Háṣábáyà, Ṣérébáyà, Jéṣúà ọmọ Kádímíélì, àti àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ wọn, tí wọ́n dúró ní ìdojúkojúu wọn láti ròyìn àti láti dúpẹ́, apá kan ń dá èkejì lóhùn, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Dáfídì ènìyàn Ọlọ́run.

25. Mátanáyà, Bákíbúkáyà, Ọbadáyà, Mésúlámù, Tálímónì àti Ákúbù ni aṣọ́nà tí wọ́n ń ṣọ yàrá ìpamọ́ ní ẹnu ibodè.

26. Wọ́n ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ ní ìgbà ayé e Jóíákímù ọmọ Jéṣúà, ọmọ Jósádákì, àti ní ọjọ́ ọ Nehemáyà baálẹ̀ àti ní ọjọ́ọ Ẹ́sírà àlùfáà àti akọ̀wé.

27. Nígbà ìyàsímímọ́ odi Jérúsálẹ́mù a mú ọmọ Léfì jáde wá láti ibi tí wọ́n ń gbé, wọ́n sì mú wọn wá sí Jérúsálẹ́mù láti fi ayọ̀ ṣe ayẹyẹ ìyàsímímọ́ pẹ̀lú orin ìdúpẹ́ àti pẹ̀lú ohun èlò orin síḿbálì, háápù àti dùùrù.

28. A kó àwọn akọrin náà jọ papọ̀ láti àwọn ìletò tí ó yí Jérúsálẹ́mù náà ká—láti àwọn abúlé Nétófátítì,

29. Láti Bétì Gílígálì, àti láti àwọn agbègbè Gébà àti Ásímáfétì, nítorí àwọn akọrin ti kọ́ àwọn ìletò fún ra wọn ní agbégbé Jérúsálẹ́mù.

30. Nígbà tí àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì ti ya ara wọn sí mímọ́, wọ́n ya àwọn ènìyàn sí mímọ́, àti ẹnu ibodè àti odi pẹ̀lú.

31. Mo sì tún yan àwọn olórí Júdà láti gun orí odi náà. Mo sì tún yan àwọn ẹgbẹ́ akọrin ńlá méjì láti dúpẹ́. Àwọn kan yóò gòkè odi lọ sí apá ọ̀tún sí ọ̀nà ibodè Ààtàn.

32. Hósáyà àti ìdajì àwọn olórí Júdà tẹ̀lé wọn,

33. Àwọn wọ̀nyí náà sì lọ pẹ̀lúu wọn, Áṣáráyà, Éṣírà, Mésúlámù,

Ka pipe ipin Nehemáyà 12