Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Náhúmù 3:8-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. Ǹjẹ́ ìwọ ha sàn ju Tébésì lọ,èyí tí ó wà ní ibi odò, Náílìtí omi sì yí káàkiri?Odò náà sì jẹ́ ààbò rẹ̀,omi si jẹ́ odi rẹ̀.

9. Etiópíà àti Éjíbítì ni agbára rẹ, kò sí ní òpin;Pútì àti Líbíà ni àwọn olùgbèjà rẹ̀.

10. Ṣíbẹ̀ ṣíbẹ̀ a kó o ní ìgbèkùno sì lọ sí oko ẹrú.Àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ rẹ̀ ni a ó fọ́ mọ́lẹ̀ní orí ìta gbogbo ìgboro.Wọ́n sì di ìbò nítorí àwọn ọlọ́lá rẹ̀ ọkùnrin,gbogbo àwọn ọlọ́lá rẹ ni a sì fi ẹ̀wọ̀n dè

11. Ìwọ pẹ̀lú yóò sì mu àmupara;a ó si fi ọ́ pamọ́ìwọ pẹ̀lú yóò máa ṣe àfẹ́rí ààbò nítorí ti ọ̀tá náà.

12. Gbogbo ilé-ìṣọ́ agbára rẹ yóò dàbí igi ọ̀pọ̀tọ́pẹ̀lú àkọ́pọ́n èso wọn;Nígbà tí wọ́n bá ń gbọ̀n wọ́n,ọ̀pọ̀tọ́ yóò sì bọ́ sí ẹnu àwọn ọ̀jẹun.

13. Kíyè sí,Obínrin ni àwọn ènìyàn rẹ ní àárin!Ojú ibodè rẹ ní a ó sí sílẹ̀ gbagada,fún àwọn ọ̀tá rẹ̀;iná yóò jó ilẹ̀ rẹ

14. Ìwọ pọn omi de ìhámọ́,mú ile ìsọ́ rẹ lágbára sí iwọ inú amọ̀kí o sì tẹ erùpẹ̀,kí ó sì tún ibi tí a ti ń sun bíríkì-amọ̀ ṣe kí ó le.

15. Níbẹ̀ ni iná yóò ti jó ọ́ run;Idà yóò sì ké ọ kúrò,yóò sì jẹ ọ́ bí i kòkòrò,yóò sì sọ ara rẹ̀ di púpọ̀ bí i tata,àní, di púpọ̀ bí eṣú!

Ka pipe ipin Náhúmù 3