Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Náhúmù 3:13-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

13. Kíyè sí,Obínrin ni àwọn ènìyàn rẹ ní àárin!Ojú ibodè rẹ ní a ó sí sílẹ̀ gbagada,fún àwọn ọ̀tá rẹ̀;iná yóò jó ilẹ̀ rẹ

14. Ìwọ pọn omi de ìhámọ́,mú ile ìsọ́ rẹ lágbára sí iwọ inú amọ̀kí o sì tẹ erùpẹ̀,kí ó sì tún ibi tí a ti ń sun bíríkì-amọ̀ ṣe kí ó le.

15. Níbẹ̀ ni iná yóò ti jó ọ́ run;Idà yóò sì ké ọ kúrò,yóò sì jẹ ọ́ bí i kòkòrò,yóò sì sọ ara rẹ̀ di púpọ̀ bí i tata,àní, di púpọ̀ bí eṣú!

16. Ìwọ ti sọ àwọn oníṣòwò rẹ di púpọ̀títí wọn yóò ṣe pọ̀ ju ìràwọ̀ oju ọ̀run lọKòkòrò na ara rẹ̀ó sì fò lọ.

17. Àwọn aládé rẹ̀ dàbí eṣú,àwọn ọ̀gágun rẹ dàbí ẹlẹ́ǹgà ńlá,èyí ti ń dó sínú ọgbà la ọjọ́ òtútù,ṣùgbọ́n nígbà tí òòrùn jáde, wọ́n sá lọẹnìkan kò sì mọ ibi tí wọ́n gbé wà.

18. Ìwọ ọba Ásíríà,àwọn olùṣọ àgùntàn rẹ̀ ń tòògbé;awọn ọlọ́lá rẹ yóò máa gbé inú ekuru.Rẹ àwọn ènìyàn rẹ fọ́nká lórí àwọn òkè ńlá,tí ẹnikẹni kò sì kó wọn jọ.

19. Kò sì sí ohun tí ó lè wo ọgbẹ́ ẹ rẹ sàn;ọgbẹ́ rẹ kun fún ìroraGbogbo ẹni tí ó bá sì gbọ́ ìròyìn rẹyóò pàtẹ́wọ́ lé ọ lórí,nítorí ni orí ta ni,ìwà buburu rẹ kò ti kọjá nígbà gbogbo?

Ka pipe ipin Náhúmù 3