Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Náhúmù 2:9-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. “Ẹ kó ìkógun fàdákà!Ẹ kó ìkógun wúrà!Ìṣúra wọn ti kò lópin náà,àti ọrọ̀ kúrò nínú gbogbo ohun èlò ti a fẹ́!”

10. Òun ti ṣòfò, ó si di asán, ó sì di ahoro:ọkàn pami, éekún ń lu ara wọn,ìrora púpọ̀ sì wà nínú gbogbo ẹgbẹ́àti ojú gbogbo wọ́n sì rẹ̀wẹ̀sì.

11. Níbo ni ihò àwọn kìnnìún wààti ibi ìjẹun àwọn ọmọ kìnnìún,níbi tí kìnnìún, àní abo kìnnìún ti ń rìn,àti ọmọ kìnnìún, láìsí ohun ìbẹ̀rù

12. Kìnnìún pàápàá tẹ́rù fún àwọn ọmọ rẹ̀,ó sì fún-un ní ọ́rùn pa fún àwọn abo kìnnìún rẹ̀,Ó sì fi ohun pípa kún ibùgbé rẹ̀àti ihò rẹ̀ fún ohun ọdẹ.

Ka pipe ipin Náhúmù 2