Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Náhúmù 2:2-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Olúwa yóò mú ọláńlá Jákọ́bù padà sípògẹ́gẹ́ bí ọláńlá Ísírẹ́lìbí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn apanirun ti pa ibẹ̀ run,tí wọ́n sì ti run àwọn àjàrà wọn.

3. Asà àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sì di pupa;àwọn ológun wọn sì wọ aṣọ òdòdó.Idẹ tí ó wà lórí kẹ̀kẹ́ ogun ń kọ mọ̀nàmọ̀nàní ọjọ́ tí a bá pèsè wọn sílẹ̀ tán;igi fìrì ni a ó sì mì tìtì.

4. Àwọn kẹ̀kẹ́ ogun yóò ya bo àwọn pópónà,wọn yóò sì máa sáré síwá àti sẹ́yìn ní àárin ìgboro.Wọn sì dàbí ètúfú iná;tí ó sì kọ bí i mọ̀nàmọ́ná.

5. Òun yóò ṣe àṣàrò àwọn ọlọ́lá rẹ̀;ṣíbẹ̀ wọ́n ń kọsẹ̀ ní ojú ọ̀nà wọn;wọn sá lọ sí ibi odi rẹ̀,a ó sì pèsè ààbò rẹ̀.

6. A ó sí ìlẹ̀kùn àwọn odò wọ̀n-ọn-nì sílẹ̀,a ó sì mú ààfin náà di yíyọ́.

7. A pa á láṣẹ pé ìlú náà Èyí tí a ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ni kí a kó ní ìgbèkùn lọ.A ó sì mú un gòkè wáàti awọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ yóò ti ohùn bí ti oriri, ṣe amọ̀nà rẹ̀,wọn a sì máa lu àyà wọn.

Ka pipe ipin Náhúmù 2