Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Málákì 2:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. “Ǹjẹ́ nísinsìn yìí, ẹ̀yin àlùfáà, òfin yìí ní fún yín.

2. Bí ẹ̀yin kò bá ni gbọ́, bí ẹ̀yin kò bá ní fi í sí àyà láti fi ọ̀wọ̀ fún orúkọ mi,” ni Olúwa àwọn ọmọ ogun wí; èmi yóò sì ran ègún sí orí yín, èmi yóò sì fi ìbùkún yín ré. Nítòótọ́ mó ti fi ré ná, nítorí pé, ẹ̀yin kò fi sí ọkàn yín láti bu ọlá fún mi.

3. “Nítorí ti yín èmí yóò ba àwọn ọmọ yín wí èmi ó sì fi ìgbẹ́ rẹ́ yín lójú, àní àwọn ìgbẹ́ ọrẹ ọwọ́ yín wọ̀nyí, a ó sì kó yín lọ pẹ̀lú rẹ̀.

4. Ẹ̀yin ó sì mọ̀ pé, èmi ni ó ti rán òfin yìí sí yín, kí májẹ̀mú mi pẹ̀lú Léfì lè tẹ́ṣíwájú” ní Olúwa àwọn ọmọ ogun wí.

5. “Májẹ̀mu mi wà pẹ̀lú rẹ̀, májẹ̀mu ti ìyè àti àlàáfíà wà pẹ̀lú rẹ̀; mo sì fi wọn fún un, nítorí bíbẹ̀rù tí ó bẹ̀rù mi, tí ẹ̀rù orúkọ mi sì bà á.

6. Òfin òtítọ́ wà ni ẹnu rẹ̀, a kò sì rí irọ́ ni ètè rẹ̀: ó ba mi rìn ní àlàáfíà àti ni ídúró ṣinṣin, ó sì yí ọ̀pọ̀lọpọ̀ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀.

Ka pipe ipin Málákì 2