Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Léfítíkù 7:18-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

18. Bí ẹ bá jẹ ọ̀kankan nínú ẹran ọrẹ àlàáfíà ní ọjọ́ kẹta, kò ni jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà. A kò ní í kà á sí fún ẹni tó rúbọ náà, nítorí pé ó jẹ́ àìmọ́, ẹnikẹ́ni tó bá sì jẹ ẹ́, ni a ó di ẹ̀bi rẹ̀ rù.

19. “ ‘Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹran tí ó bá ti kan ohun tí a kà sí àìmọ́, sísun ni kí ẹ sun ún. Ẹnikẹ́ni tí a ti kà sí mímọ́ le è jẹ nínú ẹran tí ó kù.

20. Ṣùgbọ́n bí ẹni tí kò mọ́ bá jẹ́ ẹran ọrẹ àlàáfíà tí ó jẹ́ tí Olúwa, a ó ge irú ẹni bẹ́ẹ̀ kúrò lára àwọn ènìyàn rẹ̀.

21. Bí ẹnikẹ́ni bá fọwọ́ kan ohun aláìmọ́ yálà ohun àìmọ́ ti ènìyàn, ẹranko aláìmọ́, ohun àìmọ́ yówù kí ó jẹ́ tàbí ohunkóhun tí ó jẹ́ ìríra, tí ó sì tún jẹ́ ẹran ọrẹ àlàáfíà tó jẹ́ ti Olúwa, a ó gé irú ẹni bẹ́ẹ̀ kúrò lára àwọn ènìyàn rẹ.’ ”

22. Olúwa sọ fún Mósè pé,

23. “Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: ‘Ẹ má ṣe jẹ ọ̀rá mààlúù, àgùntàn tàbí ewúrẹ́

24. Ẹ lè lo ọ̀rá ẹran tó kú fúnra rẹ̀ tàbí èyí tí ẹranko ìgbẹ́ pa, fún nǹkan mìíràn, ṣùgbọ́n ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹ́.

25. Ẹnikẹ́ni tó bá jẹ ọ̀rá ẹran tí a fi rúbọ sísun sí Olúwa ni ẹ gbọdọ̀ gé kúrò lára àwọn ènìyàn rẹ̀.

26. Ẹ kò sì gbọdọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀ ẹyẹ tàbí ẹran ní gbogbo ibi tí ẹ bá ń gbé.

27. Bí ẹnikẹ́ni bá jẹ ẹ̀jẹ̀, a ó ge ẹni bẹ́ẹ̀ kúrò lára àwọn ènìyàn rẹ̀.’ ”

Ka pipe ipin Léfítíkù 7