Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Léfítíkù 26:20-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

20. Ẹ ó máa lo agbára yín lásán torí pé ilẹ̀ yín kì yóò so èso, bẹ́ẹ̀ ni àwọn igi yín kì yóò so èso pẹ̀lú.

21. “ ‘Bí ẹ bá tẹ̀ṣíwájú láì gbọ́ tèmi, Èmi yóò tún fa ìjayà yín le ní ìgbà méje gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ yín.

22. Èmi yóò rán àwọn ẹranko búburú sí àárin yín, wọn yóò sì pa àwọn ọmọ yín, wọn yóò run agbo ẹran yín, díẹ̀ nínú yín ni wọn yóò ṣẹ́kù kí àwọn ọ̀nà yín lè di ahoro.

23. “ ‘Bí ẹ kò bá tún yípadà lẹ́yìn gbogbo ìjìyà wọ̀nyí, tí ẹ sì tẹ̀síwájú láti lòdì sí mi.

24. Èmi náà yóò lòdì sí yín. Èmi yóò tún fa ìjìyà yín le ní ìlọ́po méje ju ti ìṣáájú.

25. Èmi yóò mú ogun wá bá yín nítorí ẹ̀ṣẹ̀ yín láti fi gbẹ̀san májẹ̀mú mi tí ẹ kò pa mọ́. Bí ẹ ba sálọ sí ìlú yín fún ààbò: Èmi yóò rán àjàkálẹ̀-àrùn sí ààrín in yín: Àwọn ọ̀ta yín, yóò sì ṣẹ́gun yín.

26. Èmi yóò dá ìpèsè oúnjẹ yín dúró, débi pé: inú àrò kan ni obìnrin mẹ́wàá yóò ti máa ṣe oúnjẹ yín. Òṣùwọ̀n ni wọn yóò fi máa yọ oúnjẹ yín: Ẹ ó jẹ ṣùgbọ́n, ẹ kò ní yó.

27. “ ‘Lẹ́yìn gbogbo èyí, bí ẹ kò bá gbọ́ tèmi, tí ẹ sì lòdì sí mi,

28. Ní ìbínú mi èmi yóò korò sí yín, èmi tìkara mi yóò fìyà jẹ yín ní ìgbà méje nítorí ẹ̀ṣẹ̀ yín.

29. Ebi náà yóò pa yín débi pé ẹ ó máa jẹ ẹran ara àwọn ọmọ yín ọkùnrin, àti àwọn ọmọ yín obìnrin.

30. Èmi yóò wó àwọn pẹpẹ òrìṣà yín, lórí òkè níbi tí ẹ ti ń sìn: Èmi yóò sì kó òkú yín jọ, sórí àwọn òkú òrìṣà yín. Èmi ó sì kóríra yín.

31. Èmi yóò sọ àwọn ìlú yín di ahoro, èmi yóò sì ba àwọn ilé mímọ́ yín jẹ́. Inú mi kì yóò sì dùn sí òórùn ọrẹ yín mọ́.

Ka pipe ipin Léfítíkù 26