Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Léfítíkù 24:9-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ ló ni ín. Wọ́n gbọdọ̀ jẹ ẹ́ ní ibi mímọ́ torí pé ó jẹ́ ipa tí ó mọ́ jùlọ ti ìpín wọn ojojúmọ́ nínú ọrẹ tí a fi iná ṣe sí Olúwa.”

10. Ọmọkùnrin kan wà tí ìyá rẹ̀ jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì baba rẹ̀ sì jẹ́ ará Éjíbítì. Ó jáde lọ láàrin àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ìjà sì ṣẹlẹ̀ nínú àgọ́ láàrin òun àti ọmọ Ísírẹ́lì kan.

11. Ọmọkùnrin arábìnrin Ísírẹ́lì náà sọ̀rọ̀ òdì sí orúkọ Olúwa pẹ̀lú èpè: Wọ́n sì mú-un tọ Mósè wá. (Orúkọ ìyá rẹ̀ ní Selomiti, ọmọbìnrin Débírì, ará Dánì).

12. Wọ́n fi í sínú àtìmọ́lé kí Olúwa to sọ ohun tí wọn yóò ṣe fún wọn.

13. Olúwa sì sọ fún Mósè pé:

14. “Mú asọ̀rọ̀òdì náà jáde wá sẹ́yìn àgọ́, kí gbogbo àwọn tí ó gbọ́ pé ó ṣépè gbé ọwọ́ wọn lórí ọkùnrin náà láti fi hàn pé ó jẹ̀bi. Lẹ́yìn náà ni kí gbogbo àpéjọpọ̀, sọ ọ́ ní òkúta pa.

15. Sọ fún àwọn ará Ísírẹ́lì pé: ‘Bí ẹnikẹ́ni bá ṣépè lé Ọlọ́run rẹ̀, yóò jìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.

16. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ̀rọ̀òdì sí orúkọ Olúwa ni kí ẹ pa, kí gbogbo àpéjọpọ̀ sọ ọ́ ní òkúta pa, yálà àlejò ni tàbí ọmọbíbí Ísírẹ́lì, bí ó bá ti sọ̀rọ̀òdì sí orúkọ Olúwa, pípa ni kí ẹ pa á.

17. “ ‘Ẹni tí ó bá gba ẹmi ènìyàn pípa ni kí ẹ pa á.

18. Ẹni tí ó bá gba ẹ̀mí ẹran ọ̀sìn ẹlòmíràn, kí ó dá a padà—ẹ̀mí dípò ẹ̀mí.

19. Bí ẹnìkan bá pa ẹnìkejì rẹ̀ lára: ohunkóhun tí ó ṣe ni kí ẹ ṣe sí i.

20. Bí ó bá ṣẹ́ egungun ẹnìkan, egungun tirẹ̀ náà ni kí a ṣẹ́, bí ó bá fọ́ ojú ẹnìkan, ojú tirẹ̀ náà ni kí a fọ́, bí ó bá ká eyín ẹnìkan, eyín tirẹ̀ náà ni kí a ká. Bí ó ti pa ẹnìkejì lára náà ni kí ẹ pa òun náà lára.

21. Ẹnikẹ́ni tí ó bá pa ẹran ọ̀sìn gbọdọ̀ ṣe àtúnṣe ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá pa ènìyàn ni kí ẹ pa.

22. Òfin kan náà ló wà fún àlejò àti fún ọmọ Ísírẹ́lì. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.’ ”

Ka pipe ipin Léfítíkù 24