Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Léfítíkù 23:31-44 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

31. Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan rárá. Èyí yóò jẹ́ ìlànà ayérayé fún àwọn ìran tí ń bọ̀, níbikíbi tí ẹ bá ń gbé.

32. Ọjọ́ ìsinmi ni fún yín, ẹ gbọdọ̀ ṣẹ́ ara yín, láti ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kẹsàn-án oṣù náà, títí di ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ tí ó tẹ̀ lé e, ni kí ẹ fi sinmi.”

33. Olúwa sọ fún Mósè pé,

34. “Sọ fún àwọn ará Ísírẹ́lì pé: ‘Ní ọjọ́ kẹẹdógún oṣù keje ni kí àjọ̀dún ọdún Àgọ́ ti Olúwa bẹ̀rẹ̀ kí ó sì wà títí di ọjọ́ méje.

35. Ọjọ́ kìn-ín-ní jẹ́ ọjọ́ ìpàdé mímọ́: ṣẹ kò gbọdọ̀ e iṣẹ́ ojúmọ́.

36. Ọjọ́ méje ni kí ẹ fi mú ọrẹ tí a fi iná ṣe wá, ní ọjọ́ kẹjọ ẹ pe ìpàdé mímọ́ kí ẹ sì mú ọrẹ tí a fi iná ṣe wá fún Olúwa, èyí jẹ́ ìpàdé tí ó gbẹ̀yìn; ẹ má ṣe ṣe iṣẹ́ ojojúmọ́.

37. (“ ‘Ìwònyí ni àwon àjọ̀dún tí Olúwa ti yàn tí ẹ gbọdọ̀ kéde gẹ́gẹ́ bí i ìpàdé mímọ́ fún mímu àwọn ọrẹ tí a fi iná ṣe sí Olúwa wá—ọrẹ sísun àti ọrẹ ọkà, ọrẹ ẹbọ àti ọrẹ ohun mímu, fún ọjọ́ kọ̀ọ̀kan:

38. Àwọn ọrẹ wọ̀nyí wà ní àfikún pẹ̀lú àwọn ọrẹ ọjọ́ ìsinmi Olúwa, àti pẹ̀lú ẹ̀bùn yín àti ohunkóhun tí ẹ ti jẹ́jẹ̀ẹ́ àti gbogbo ọrẹ àtinúwá yín fún Olúwa.)

39. “ ‘Torí náà, bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́ kẹẹ̀dógún osù kéje lẹ́yìn ìgbà tí ẹ ti kórè ilẹ̀ náà, ẹ se àjọ̀dún yìí fún Olúwa ní ọjọ́ méje. Ọjọ́ kìn-ín-ní jẹ́ ọjọ́ ìsinmi, ọjọ́ kẹjọ pẹ̀lú si tún jẹ́ ọjọ́ ìsinmi.

40. Ní ọjọ́ kìn-ín-ní kí ẹ mú àṣàyàn èso láti orí igi, igi tẹ́ẹ́rẹ́ etídò, àti ẹ̀ka igi tó rúwé, kí ẹ sì máa yọ̀ níwájú Olúwa Ọlọ́run yín fún ọjọ́ méje.

41. Ẹ ṣe èyí ní àjọ̀dún sí Olúwa fún ọjọ́ méje lọ́dọọdún. Èyí yóò jẹ́ ìlànà ayérayé fún àwọn ìran tí ń bọ̀: Ẹ ṣe é ní oṣù keje.

42. Ẹ gbé inú àgọ́ fún ọjọ́ méje. Kí gbogbo ọmọbíbí Ísírẹ́lì gbé nínú àgọ́.

43. Kí àwọn ìran yín le mọ̀ pé mo mú kí Ísírẹ́lì gbé nínú àgọ́, nígbà tí mo mú wọn jáde ní Éjíbítì. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.’ ”

44. Báyìí ni Mósè kéde àwọn àṣàyàn ọdún Olúwa fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.

Ka pipe ipin Léfítíkù 23