Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Léfítíkù 13:22-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

22. Bí ó bá ràn ká: awọ ara, kí àlùfáà pe ẹni náà ní aláìmọ́. Àrùn tí ó ń ràn ni èyí.

23. Ṣùgbọ́n bí ojú ibẹ̀ kò bá yàtọ̀, tí kò sì ràn kára: èyí jẹ́ àpa oówo lásán: kí àlùfáà pe ẹni náà ni mímọ́.

24. “Bí iná bá jó ẹnìkan tí àmì funfun àti pupa sì yọ jáde lójú egbò iná náà.

25. Kí àlùfáà yẹ ojú ibẹ̀ wò. Bí irun ibẹ̀ bá ti di funfun tí ó sì jinlẹ̀ ju àwọ̀ ara lásán lọ, àrùn tí ń ràn ká ti wọ ojú iná náà, kí àlùfáà pè é ní aláìmọ́. Àrùn tí ń ran ni ni èyí.

26. Ṣùgbọ́n bí àlùfáà bá yẹ̀ ẹ́ wò tí kò sí irun funfun lójú egbò náà tí kò sì jinlẹ̀ ju àwọ̀ ara lọ tí ó sì ti gbẹ, kí àlùfáà fi ẹni náà pamọ́ fún ọjọ́ méje.

27. Kí àlùfáà yẹ ẹni náà wò ní ọjọ́ keje, bí ó bá ń ràn ká àwọ̀ ara, kí àlùfáà kí ó pè é ní aláìmọ́. Àrùn ara tí ń ràn ni èyí.

28. Ṣùgbọ́n bí ojú iná náà kò bá yípadà tí kò sì ràn ká àwọ̀ ara. Ṣùgbọ́n tí ó gbẹ: ìwú lásán ni èyí láti ojú iná náà; kí àlùfáà pè é ní mímọ́. Ojú àpá iná lásán ni.

29. “Bí ọkùnrin tàbí obìnrin kan bá ní egbò lórí tàbí ní àgbọ̀n.

30. Kí àlùfáà yẹ̀ ẹ́ wò bí ó bá jinlẹ̀ ju àwọ̀ ara lọ tí irun ibẹ̀ sì pọ́n fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ tí kò sì kún; kí àlùfáà pe ẹni náà ní aláìmọ́; làpálàpá ni èyí. Àrùn tí ń ràn ká orí tàbí àgbọ̀n ni.

31. Ṣùgbọ́n bí àlùfáà bá yẹ egbò yìí wò tí kò sì jinlẹ̀ ju àwọ̀ ara lọ tí kò sì sí irun dúdú kan níbẹ̀. Kí àlùfáà fi ẹni náà pamọ́ fún ọjọ́ méje.

Ka pipe ipin Léfítíkù 13