Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Léfítíkù 12:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Olúwa sọ fún Mósè pé,

2. “Sọ fún àwọn ará Ísírẹ́lì pé: ‘Obìnrin tí ó bá lóyún tí ó sì bí ọmọkùnrin, yóò wà láìmọ́ fún ọjọ́ méje bí ìgbà tí ó wà ní ipò àìmọ́ lákókò nǹkan oṣù rẹ̀.

3. Ní ọjọ́ kẹjọ ni kí ẹ kọ ọmọ náà ní ilà.

4. Obìnrin náà yóò sì dúró fún ọjọ́ mẹ́talélọ́gbọ̀n (33) láti di mímọ́ kúrò nínú ìsun ẹ̀jẹ̀ rẹ̀. Kò gbọdọ̀ fi ọwọ́ kan ohunkóhun tí ó jẹ́ mímọ́ tàbí kí ó lọ sí ibi mímọ́ Olúwa títí di ọjọ́ tí ìwẹ̀nùmọ́ rẹ̀ yóò kọjá.

Ka pipe ipin Léfítíkù 12