Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Léfítíkù 10:5-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Wọ́n sì wá gbé wọn, pẹ̀lú ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ wọn ní ọrùn wọn lọ sí ẹ̀yìn ibùdó bí Mósè ti sọ.

6. Mósè sọ fún Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ yóòkù, Élíásárì àti Ítamárì pé, “ẹ má ṣe sọ̀fọ̀ nípa ṣíṣe aláìtọ́jú irun yín tàbí kí ẹ sí orí yín sílẹ̀, ẹ kò sì gbọdọ̀ ya aṣọ, bí ẹ bá ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ ó kùú, Olúwa yóò sì bínú sí gbogbo ìjọ ènìyàn. Ṣùgbọ́n àwọn ẹbí yín, àti gbogbo ilé Ísírẹ́lì le è ṣọ̀fọ̀ lórí àwọn tí Olúwa fi iná parun.

7. Ẹ má ṣe kúrò ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé, bí ẹ bá kúrò níbẹ̀, ẹ ó kùú, nítorí pé òróró ìtasórí Olúwa wà lórí yín” Wọ́n sì ṣe bí Mósè ti wí.

8. Olúwa sì sọ fún Árónì pé.

9. “Ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ̀ kò gbọdọ̀ mu ọtí wáìnì tàbí ọtí líle mìíràn nígbàkigbà tí ẹ bá n lọ inú àgọ́ ìpàdé, bí ẹ bá ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ ó kùú, èyí jẹ́ ìlànà títí láé fún un yín láti ìrandíran.

10. Ẹ gbọdọ̀ mọ ìyàtọ̀ láàrin mímọ́ àti àìmọ́, láàrin èérí àti àìléérí.

11. Ẹ gbọdọ̀ kọ́ àwọn ara Ísírẹ́lì ní gbogbo àṣẹ tí Olúwa fún wọn láti ẹnu Mósè.”

Ka pipe ipin Léfítíkù 10