Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóṣúà 20:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Jósúà pé,

2. “Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọn yan àwọn ìlú ààbò, gẹ́gẹ́ bí mo ti pàṣẹ fún ọ láti ẹnu Mósè,

3. kí ẹni tí ó bá sèèsì pa ènìyàn tàbí tí ó bá pa ènìyàn láìmọ̀ọ́mọ̀ lè sálọ sí ibẹ̀, fún ààbò lọ́wọ́ olùgbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ ẹni tí ó pa.

4. “Nígbà tí ó bá sálọ sí ọ̀kan nínú àwọn ìlú wọ̀nyí, yóò sì dúró ní ẹnu ọ̀nà àtiwọ ibodè ìlú, kí ó sì ṣe àlàyé ara rẹ̀ ní iwájú àwọn àgbààgbà ìlú náà. Nígbà náà ni wọn yóò gbà á sí ìlú wọn, wọn yóò sì fun ní ibùgbé láàárin wọn.

Ka pipe ipin Jóṣúà 20