Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóṣúà 19:11-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Ó sì lọ sí ìwọ̀-oòrùn ní Márálà, ó sì dé Dábésẹ́tì, ó sì lọ títí dé Ráfénì odo ní ẹ̀bá Jókíníámù.

12. Ó sì yípadà sí ìlà-oòrùn láti Sérídì sí ìhà ìlà-oòrùn dé ilẹ̀ Kisiloti-Tábórì, ó sì lọ sí Dábérátì, ó sì gòkè lọ sí Jáfíà.

13. Nígbà náà ní o lọ sí ìhà ìlà-oòrùn lọ sí Gati-Héférì àti Eti-Kásínì, ó sì jáde ní Rímónì, ó sì yí sí ìhà Níà.

14. Ní ibẹ̀, ààlà sì yí ká ní ìhà àríwá lọ sí Hánátónì ó sì pin ní Àfonífojì Ifita Élì.

15. Lára wọn ni Kátatì, Náhalálì, Símírónì, Ìdálà àti Bẹ́tílẹ́hẹ́mù. Wọ́n sì jẹ́ ìlú méjìlá àti ìletò wọn.

16. Ìlú wọ̀nyí àti ìletò wọn jẹ́ ìní Sébúlunì, ní agbo ilé agbo ilé.

17. Gègé kẹrin jáde fún Ísákárì, agbo ilé ní agbo ilé.

18. Lára ilẹ̀ wọn ni èyí:Jésíréélì, Késúlótì, Súnemù,

19. Háfáráímù, Ṣíhónì, Ánáhárátì,

20. Rábítì, Kíṣíónì, Ébésì,

21. Rémétì, Ẹni-Gánnímù, Ẹni-Hádà àti Bẹ́tì-Pásésì.

22. Ààlà náà sì dé Tábórì, Ṣáhásúmà, àti Bẹti Ṣẹ́mẹ́ṣì, ó sì pin ní Jọ́dánì. Wọ́n sì jẹ́ ìlú mẹ́rindínlógún àti iletò wọn.

23. Ìlú wọ̀nyí àti iletò wọn jẹ́ ìní ẹ̀yà Ísákárì, ní agbo ilé agbo ilé.

Ka pipe ipin Jóṣúà 19