Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóṣúà 18:1-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Gbogbo ìjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì péjọ ní Ṣílò, wọ́n si kó Àgọ́ Ìpàdé ní ibẹ̀ Gbogbo ilẹ̀ náà sì wà ní abẹ́ àkóso wọn,

2. ṣùgbọ́n ó ku ẹ̀yà méje nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí kò tí ì gba ogún ìní wọn.

3. Báyìí ni Jóṣúà sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì: “Báwo ni ẹ̀yin yóò ṣe dúró pẹ́ tó, kí ẹ tó gba ilẹ̀ ìní tí Olúwa, Ọlọ́run àwọn baba yín ti fi fún yín?

4. Ẹ yan àwọn ọkùnrin mẹ́ta nínú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan. Èmi yóò rán wọn jáde láti lọ bojúwo ilẹ̀ náà káàkiri, wọn yóò sì ṣe àpèjúwe rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìní ẹni kọ̀ọ̀kan. Nígbà náà ni wọn yóò padà tọ̀ mí wá.

5. Ẹ̀yin yóò sì pín ilẹ̀ náà sí ọ̀nà méje kí Júdà dúró sí ilẹ̀ rẹ̀ ni ìhà gúsù àti ilé Jósẹ́fù ní ilẹ̀ rẹ̀ ní ìhà àríwá.

6. Lẹ́yìn ìgbà tí ẹ bá kọ àpèjúwe ọ̀nà méjèèje ilẹ̀ náà, ẹ mú wọn wá sí ọ̀dọ̀ mi ní ibí, èmi ó sì ṣẹ́ gègé fún yín ní iwájú Olúwa Ọlọ́run wa.

7. Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Léfì kò ní ìpín ní àárin yín, nítorí iṣẹ́ àlùfáà. Olúwa ni ìní wọ́n. Gádì, Rúbẹ́nì àti ìdajì ẹ̀yà Mánásè, ti gba ìní wọn ní ìhà ìlà-oòrùn Jọ́dánì. Mósè ìránṣẹ́ Olúwa ti fi fún wọn.”

8. Bí àwọn ọkùnrin náà ti bẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò wọn láti fojú díwọ̀n ilẹ̀ náà, Jóṣúà pàṣẹ fún wọn pé, “Ẹ lọ kí ẹ sì fojú díwọ̀n ilẹ̀ náà kákiri, kí ẹ sì kọ àpèjúwe rẹ̀. Lẹ́yìn náà kí ẹ padà tọ̀ mí wá, èmi yóò sì fún yin ní ibí ní Sílòi ní iwájú Olúwa.”

9. Báyìí ni àwọn ọkùnrin náà lọ, wọ́n sì la ilẹ̀ náà já. Wọ́n sì kọ àpèjúwe rẹ̀ sí orí ìwé kíká ní ìlú, ní ọ̀nà méje, wọ́n sì padà tọ Jóṣúà lọ ní ibùdó ní Ṣílò.

10. Jóṣúà sì ṣẹ́ gègé fún wọn ní Sílò ní iwájú Olúwa, Jóṣúà sì pín ilẹ̀ náà fún àwọn Ísírẹ́lì gẹ́gẹ́ bí ìpín ẹ̀yà wọn ní ibẹ̀.

11. Ìbò náà sì wá sórí ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì, ní agbo ilé, agbo ilé. Ilẹ̀ ìpín wọn sì wà láàárin ti ẹ̀yà Júdà àti Jósẹ́fù:

12. Ní ìhà àríwá ààlà wọn bẹ̀rẹ̀ ní Jọ́dánì, ó kọjá lọ sí gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Jẹ́ríkò ní ìhà àríwá, ó sì forílé ìwọ̀-oòrùn sí ìlú òkè, jáde sí asálẹ̀ Bẹti-Áfẹ́nì.

13. Láti ibẹ̀ ààlà náà tún kọjá lọ sí ìhà gúsù ní ọ̀nà Lúsì, (èyí ni Bẹ́tẹ́lì) ó sìdé Afaroti-Ádárì, ní orí òkè tí ó wà ní gúsù Bẹti-Hórónì

14. Láti òkè tí ó kọjú sí Bẹti-Hórónì ní gúsù ààlà náà yà sí gúsù ní ìhà ìwọ̀-oòrùn, ó sì jáde sí Kiriati-Báálì (tí í ṣe Kiriati-Jéárímù), ìlú àwọn ènìyàn Júdà. Èyí ni ìhà ìwọ̀-oòrùn.

15. Ìhà gúsù bẹ̀rẹ̀ ní ìpẹ̀kun Kiriati-Jéárímù ní ìwọ̀-oòrùn, ààlà náà wà ní ibi ìsun omi Nẹ́fítóà.

Ka pipe ipin Jóṣúà 18