Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóṣúà 17:10-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Ìhà gúsù ilẹ̀ náà jẹ́ ti Éfúráímù, ṣùgbọ́n ìhà àríwá jẹ́ ti Mánásè. Ilẹ̀ Mánásè dé òkun, Ásérì sì jẹ́ ààlà rẹ̀ ní àríwá, nígbà Ísákárì jẹ́ ààlà ti ìlà-oòrùn.

11. Ní àárin Ísákárì àti Ásérì, Mánásè tún ni Bẹti-Ṣánì, Íbílémù àti àwọn ènìyàn Dórì, Énídórì, Táánákì àti Mégídò pẹ̀lú àwọn abúlé tí ó yí wọn ká (ìkẹ́ta nínú orúkọ wọn ní Náfótì).

12. Ṣíbẹ̀, àwọn ọmọ Mánásè kò lè gba àwọn ìlú wọ̀nyí, nítorí àwọn ará Kénánì ti pinnu láti gbé ní ilẹ̀ náà.

13. Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn ará Ísírẹ́lì di alágbára, wọ́n mú àwọn ọmọ Kénánì sìn, ṣùgbọ́n wọn kò lé wọn jáde pátapáta.

14. Àwọn ẹ̀yà Jósẹ́fù méjèèje sì sọ fún Jóṣúà pé, “Kí ló dé ìwọ fi fún wa ní ìpín ilẹ̀ kan àti ìdá kan ní ìní? Nítorí àwa jẹ́ ọ̀pọ̀ ènìyàn tí Olúwa ti bùkún lọ́pọ̀lọpọ̀.”

15. Jóṣúà dá wọn lóhùn pé, “Bí ẹ bá pọ̀ bẹ́ẹ̀, tí òkè ìlú Éfúráímù bá kéré fún yin, ẹ gòkè lọ sí igbó kí ẹ sì sán ilẹ̀ òkè fún ara yín ní ibẹ̀ ní ilẹ̀ àwọn ará Pérísì àti ará Réfì.”

16. Àwọn ènìyàn Jósẹ́fù dáhùn, “Òkè kò tó fún wa, bẹ́ẹ̀ ni gbogbo àwọn ará Kénánì tí ó gbé ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, àti gbogbo àwọn tí ń bẹ ní Bẹti-Ṣánì àti àwọn ìletò àti àwọn tí ń gbé ní àfonífojì Jésírẹ́ẹ́lì ní kẹ̀kẹ́ ogun onírin.”

17. Ṣùgbọ́n Jóṣúà sọ fún àwọn ilé Jósẹ́fù: fún Éfúráímù àti Mánásè pé, “Lóòtọ́ ni ẹ pọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀, ẹ sì jẹ́ alágbára. Ẹ̀yin kí yóò sì ní ìpín kan ṣoṣo.

18. Ṣùgbọ́n ilẹ̀ orí òkè igbo jẹ́ tiyín pẹ̀lú. Ẹ ṣán ilẹ̀ náà, òpin rẹ̀ yóò jẹ́ tiyín pátapáta. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ará Kénánì ní kẹ̀kẹ́ ogun irin, tí ó sì jẹ́ pé wọ́n ní agbára, ṣíbẹ̀ ẹ lè lé wọn jáde.”

Ka pipe ipin Jóṣúà 17