Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóṣúà 15:11-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Ààlà náà sì lọ sí gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ àríwá òkè Ékírónì, ó sì yípadà lọ sí Síkerónì, ó sì yípadà lọ sí Okè Báálà, ó sì dé Jábínẹ́ẹ́lì, ààlà náà sì parí sí òkun.

12. Ààlà ìwọ̀-oòrùn sì jẹ́ agbégbé Òkun ńlá.Ìwọ̀nyí ni ààlà àyíká ènìyàn Júdà ní agbo ilé wọn.

13. Gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí Olúwa pa fún Jóṣúà, ó fi ìpín fún Kélẹ́bù ọmọ Jéfúnè, ipin ní Júdà-Kiriati Áríbà, tí í ṣe Hébúrónì. (Áríbà sì ní baba ńlá Ánákì.)

14. Kélẹ́bù sì lé àwọn ọmọ Ánákì mẹ́ta jáde láti Hébúrónì-Ṣéṣáyì, Áhímónì, àti Tálímáì-ìran Ánákì.

15. Ó sì wọ́de ogun láti ibẹ̀ lọ bá àwọn ènìyàn tí ń gbé ní Débírì (tí à ń pè ní Kiriati Séferì tẹ́lẹ̀).

16. Kélẹ́bù sì wí pé, “Èmi yóò fi ọmọbìnrin mi Ákísà fún ọkùnrin tí ó bá kọlu Kiriati Séférì, tí ó sì gbà á ní ìgbeyàwó.”

17. Ótíniẹ́lì ọmọ Kénásì, arákùnrin Kélẹ́bù, sì gbà á, báyìí ni Kélẹ́bù sì fi ọmọbìnrin rẹ̀ Ákísà fún un ní ìyàwó.

18. Ní ọjọ́ kan, nígbà tí Ákísà lọ sí ọ̀dọ̀ Ótíniẹ̀lì, ó rọ̀ ọ́ kí ó béèrè ilẹ̀ oko lọ́wọ́ baba rẹ̀. Nígbà nàà ni Ákísà sọ̀kalẹ̀ ní orí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀, Kélẹ́bù sì béèrè pé, “Kí ni kí èmi ṣe fún ọ?”

Ka pipe ipin Jóṣúà 15