Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóṣúà 14:10-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. “Bí Olúwa ti ṣe ìlérí, o ti mú mi wà láàyè fún ọdún márùn-úndínláàádọ́ta láti ìgbà tí ó ti sọ fún Mósè. Nígbà tí Ísírẹ́lì ń rìn kiri nínú aṣálẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni èmi náà sì nìyí lónìí, ọmọ ọgọ́rin ọdún ó lé márùn-ún.

11. Síbẹ̀ èmi ní agbára lónìí, bí ìgbà tí Mósè rán mi jáde. Èmi sì ní agbára láti jáde fún ogun nísinsìnyí gẹ́gẹ́ bí mo ti wà ní ígbà náà.

12. Nísinsìnyí fi ìlú orí òkè fún mi èyí tí Olúwa ṣe ìlérí fún mi ní ọjọ́ náà. Ìwọ gbọ́ ní ìgbà náà pé àwọn ọmọ Ánákì ti wà ní ibẹ̀, àti àwọn ìlú wọn tóbi, pé ó sì se olódi, ṣùgbọ́n bí Olúwa ba fẹ́, èmi yóò lé wọn jáde, gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ.”

13. Bẹ́ẹ̀ ni Joṣua súre fun Kélẹ́bù ọmọ Jéfún ó si fun un ní Hébúrónì ni ilẹ̀ ìni

14. Bẹ́ẹ̀ ni Hébúrónì jẹ́ ti Kélẹ́bù ọmọ Jéfúnè ará Kánísì láti ìgbà náà, nítorí tí ó tẹ̀lé Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì tọkàntọkàn.

15. (Hébúrónì a sì máa jẹ́ Kíríàtì Áríbà ní ẹ̀yìn Áríbà, èyí tí ó jẹ́ ènìyàn ńlá nínú àwọn ọmọ Ánákì.)Nígbà náà ni ilẹ̀ náà sinmi ogun.

Ka pipe ipin Jóṣúà 14