Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóṣúà 13:1-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nígbà tí Jóṣúà sì darúgbó tí ọjọ́ orí rẹ̀ sì pọ̀ jọjọ, Olúwa sọ fún un pé, “Ìwọ ti darúgbó púpọ̀, bẹ́ẹ̀ ni ilẹ̀ sì kù lọ́pọ̀lọpọ̀ fún yín láti gbà.

2. “Èyí ni ilẹ̀ tí ó kù: gbogbo àwọn agbègbè àwọn Fílístínì, àti ti ara Gésúrì:

3. láti odò Ṣíhónì ní ìlà oòrùn Éjíbítì sí agbégbé Ékírónì ìhà àríwá, gbogbo rẹ̀ ni a kà kún Kénánì (agbégbé ìjòyè Fílístínì márùnún ní Gásà, Ásídódù, Áṣíkélónì, Gátì àti Ékírónì ti àwọn ará Áfítì):

4. láti gúsù, gbogbo ilẹ̀ àwọn ará Kénánì, láti Árà ti àwọn ará Sídónì títí ó fi dé Áfékì, agbègbè àwọn ará Ámórì,

5. Àti ilẹ̀ àwọn ara Gíbálì, àti gbogbo àwọn Lẹ́bánónì dé ìlà-oòrùn, láti Baalì-Gádì ní ìṣàlẹ̀ Okè Hámónì dé Lebo-Hámátì.

6. “Ní ti gbogbo àwọn olùgbé agbégbé òkè, láti Lẹ́bánónì sí Mísiréífótì-Máímù, àní, gbogbo àwọn ará Sídónì, èmi fúnra mi ní yóò lé wọn jáde ní iwájú àwọn ará Ísírẹ́lì. Kí o ri dájú pé o pín ilẹ̀ yí fún Ísírẹ́lì ní ilẹ̀ ìní, gẹ́gẹ́ bí mo ṣe fi àṣẹ fún ọ,

7. pín ilẹ̀ yìí ní ilẹ̀-ìní fún àwọn ẹ̀yà mẹ́sàn án àti ìdajì ẹ̀yà Mànásè.”

8. Àwọn ìdajì ẹ̀yà Mánásè tí ó kù, àti àwọn Rúbẹ́nì àti àwọn Gádì ti gba ilẹ̀ ìní, tí Mósè ti fún wọn ní ìhà ìlà-oòrùn Jọ́dánì bí Mósè ìránṣẹ́ Olúwa ti fi fún wọn.

9. Ó sì lọ títí láti Áreórì tí ń bẹ létí Ánónì-Gógì, àti láti ìlú náà tí ń bẹ ní àárin Gógì, àti pẹ̀lú gbogbo pẹ̀tẹ́lẹ̀ Médébà títí dé Díbónì.

10. Gbogbo ìlú Síhónì ọba àwọn Ámórì, tí ó ṣe àkóso ní Hésíbónì, títí dé ààlà àwọn ará Ámónì.

11. Àti Gílíádì, ní agbégbé àwọn ènìyàn Gésúrì àti Máákà, gbogbo Okè Hámónì àti gbogbo Básánì títí dé Sálẹ́kà,

12. Ìyẹn, gbogbo ilẹ̀ ọba Ógù ní Básánì, tí ó jọba ní Áṣítarótù àti Édérì, ẹni tí ó kù nínú àwọn Réfáítì ìyókù. Mósè ti ṣẹ́gun wọn, ó sì ti gba ilẹ̀ wọn.

13. Ṣùgbọ́n àwọn ará Ísírẹ́lì kò lé àwọn ará Géṣúrì àti Máákà jáde, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń gbé ní àárin àwọn ará Ísírẹ́lì títí di òní yìí.

14. Ṣùgbọ́n àwọn ẹ̀yà Léfì ni kò fi ogún kankan fún, níwọ̀n ìgbà tí ó ti jẹ́ pé ọrẹ àfinásun sí Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì ni ogún tiwọn, gẹ́gẹ́ bí o ti ṣèlérí fún wọn.

15. Èyí ni Mósè fi fún ẹ̀yà Rúbẹ́nì ni agbo ilé sí agbo ilé:

Ka pipe ipin Jóṣúà 13