Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóṣúà 11:10-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Ní àkókò náà Jóṣúà sì padà sẹ́yìn, ó sì ṣẹ́gun Hásórù, ó sì fi idà pa ọba rẹ̀. (Hásóri tí jẹ́ olú fún gbogbo àwọn ìlú wọ̀nyí Kó tó di àkókò yí.)

11. Wọ́n sì fi idà pa gbogbo àwọn ènìyàn tí ó wà ní ibẹ̀. Wọ́n sì pa wọ́n run pátapáta, wọn kò sì fi ohun alàyè kan sílẹ̀; ó sì fi iná sun Hásóri fúnrarẹ̀.

12. Jóṣúà sì kó gbogbo àwọn ìlú ọba àti ọba wọn, ó sì fi idà pa wọ́n. Ó sì run gbogbo wọn, gẹ́gẹ́ bí Mósè ìránṣẹ́ Olúwa ti pàṣẹ.

Ka pipe ipin Jóṣúà 11