Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóòbù 2:4-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Sàtánì sì dá Olúwa lóhùn wí pé, “Awọ fún awọ; àní ohun gbogbo tí ènìyàn ní, òun ni yóò fi ra ẹ̀mí rẹ̀.

5. Ṣùgbọ́n nawọ́ rẹ nísinsìn yìí, kí ó tọ́ egungun rẹ̀ àti ara rẹ̀, bí kì yóò sì bọ́hùn ní ojú rẹ.”

6. Olúwa sì wí fún Sàtánì pé, “Wò ó, Ó ń bẹ ní ìkàwọ́ rẹ, ṣùgbọ́n dá ẹ̀mí rẹ̀ sí.”

7. Bẹ́ẹ̀ ni Sàtánì jáde lọ kúrò níwájú Olúwa, ó sì sọ Jóòbù ní oówo kíkan kíkan láti àtẹ́lẹṣẹ̀ títí dé àtàrí rẹ̀

8. Ó sì mú àpáàdì, ó fi ń ha ara rẹ̀, ó sì jókòó nínú eérú.

9. Nígbà náà ni aya rẹ̀ wí fún-un pé, “Ìwọ di ìwà òtítọ́ mú síbẹ̀! Bú Ọlọ́run, kí ó sì kú!”

10. Ṣùgbọ́n ó dá a lóhùn pé, “Ìwọ sọ̀rọ̀ bí ọ̀kan lára àwọn obìnrin aláìmọ́ye ti í sọ̀rọ̀; há bà! Àwa yóò ha gba ire lọ́wọ́ Ọlọ́run, kí a má sì gba ibi?”Nínú gbogbo èyí, Jóòbù kò fi ètè rẹ̀ ṣẹ̀.

11. Nígbà tí àwọn ọ̀rẹ́ Jóòbù mẹ́ta gbúròó gbogbo ibi tí ó bá a, wọ́n wá, olúkúlùkù láti ibùjókòó rẹ̀; Élífásì, ara Témà àti Bílídádì, ara Ṣúà, àti Sófárì, ará Náámù: nítorí pé wọ́n ti dájọ́ ìpàdé pọ̀ láti bá a sọ̀fọ̀ àti láti sìpẹ̀ fún un.

12. Nígbà tí wọ́n gbójú wọn wò ní òkèrè réré, tí wọ́n kò sì mọ̀ ọ́n, wọ́n gbé ohùn wọn sókè, wọ́n sọkún: olúkúlùkù sì fa àṣọ ìgúnwà rẹ̀ ya, wọ́n sì ku erùpẹ̀ sí ojú ọ̀run, wọ́n sì tẹ́ orí gbà á.

Ka pipe ipin Jóòbù 2