Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jónà 1:9-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Òun sì dá wọn lóhùn pé, “Hébérù ni èmi, mo sì bẹ̀rù Olúwa, Ọlọ́run ọ̀run ẹni tí ó dá òkun àti ìyàngbẹ ilẹ̀.”

10. Nígbà náà ni àwọn ọkùnrin náà bẹ̀rù gidigidi, wọn sì wí fún un pé, “Èéṣe tí ìwọ fi ṣe èyí?” (Nítorí àwọn ọkùnrin náà mọ̀ pé ó ń sá kúrò ní iwájú Olúwa ni, nítorí òun ti sọ fun wọn bẹ́ẹ̀.)

11. Nígbà náà ni wọ́n wí fún un pé, “Kí ni kí àwa ó se sí ọ kí òkun lè dákẹ́ fún wa?” Nítorí òkun ru, ó sì ja ẹ̀fúùfù líle.

12. Òun sì wí fún wọn pé, “Ẹ gbé mi, kí ẹ sì sọ mi sínú òkun, bẹ́ẹ̀ ni okun yóò sì dákẹ́ fún un yin. Nítorí èmi mọ̀ pé, nítorí mi ni ẹ̀fúùfù líle yìí ṣe dé bá a yín.”

13. Ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin náà wà á kíkan láti mú ọkọ̀ wà sí ilẹ̀: ṣùgbọ́n wọn kò lè ṣe é: nítorí tí òkun túbọ̀ ru síi, ó sì ja ẹ̀fúùfù líle sí wọn.

14. Nítorí náà wọ́n kígbe sí Olúwa, wọ́n sì wí pé, “Olúwa àwa bẹ̀ ọ́, má ṣe jẹ́ kí àwa ṣègbé nítorí ẹ̀mí ọkùnrin yìí. Má sì ka ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sí wa ní ọrùn, nítorí ìwọ, Olúwa, ti ṣe bí ó ti wù ọ́.”

15. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n gbé Jónà, tí wọ́n sì sọ ọ́ sínú òkun, òkun sì dẹ́kun ríru rẹ̀.

16. Nígbà náà ni àwọn ọkùnrin náà bẹ̀rù Olúwa gidigidi, wọn si rúbọ sí Olúwa, wọ́n sì jẹ́ ẹ̀jẹ́.

17. Ṣùgbọ́n Olúwa ti pèṣè ẹja ńlá kan láti gbé Jónà mì. Jónà sì wà nínú ẹja náà ni ọ̀sán mẹ́ta àti òru mẹ́ta.

Ka pipe ipin Jónà 1