Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóẹ́lì 1:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó tọ Jóẹ́lì ọmọ Pétúélì wá.

2. Ẹ gbọ́ èyí ẹ̀yin àgbààgbà;ẹ fi etí sílẹ̀ gbogbo ẹ̀yin ènìyàn ará ilẹ̀ náà.Ǹjẹ́ irú èyí ha wà ní ọjọ́ yín,tàbí ní ọjọ́ àwọn baba yín?

3. Ẹ sọ ọ́ fún àwọn ọmọ yín,ki àwọn ọmọ yín sọ fún àwọn ọmọ wọn,ki àwọn ọmọ wọn sọ fún àwọn ìran mìíràn.

4. Èyí tí eṣú tí agénijẹ jẹ kùní ọ̀wọ́ eṣú jẹÈyí tí ọ̀wọ́ eṣú jẹ kùní eṣú tata jẹÈyí tí eṣú tata jẹ kùni eṣú apanirun mìíràn jẹ

Ka pipe ipin Jóẹ́lì 1