Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 9:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Áà! Orí ìbá jẹ́ orísun omi kí ojú mi sì jẹ́ orísun omijéÈmi yóò sì sunkún tọ̀sán tòrunítorí pípa àwọn ènìyàn mi.

2. Áà! èmi ìbá ní ilé àgbàwọ̀ fúnàwọn arìnrìn-àjò ní ihà kí nba à lè fi àwọn ènìyàn mi sílẹ̀kí n sì lọ kúrò lọ́dọ̀ wọn:nítorí gbogbo wọn jẹ́ pańṣágààjọ aláìsòótọ́ ènìyàn ni wọ́n.

3. Wọ́n ti pèsè ahọ́n wọn sílẹ̀ bí ọfàláti fi pa irọ́; kì í ṣe nípa òótọ́ni wọ́n fi borí ní ilẹ̀ náà. Wọ́n ńlọ láti inú ẹ̀ṣẹ̀ kan sí òmíràn,wọn kò sì náání mi,ní Olúwa wí.

4. Ṣọ́ra fún àwọn ọ̀rẹ́ rẹ; má ṣegbẹ́kẹ̀lé àwọn arákùnrin rẹnítorí pé oníkálukú arákùnrinjẹ́ atannijẹ, oníkálukú ọ̀rẹ́ sì jẹ́ abanijẹ́.

5. Ọ̀rẹ́ ń dalẹ̀ ọ̀rẹ́. Kò sì sí ẹnitó sọ òótọ́, wọ́n ti kọ́ ahọ́n wọnláti máa purọ́. Wọ́n sọ ara wọndi onírẹ̀wẹ̀sì pẹ̀lú ẹ̀ṣẹ̀

6. Ó ń gbé ní àárin ẹ̀tànwọ́n kọ̀ láti mọ̀ mí nínúẹ̀tàn wọn,ni Olúwa wí.

7. Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Àwọn ọmọ ogun wí:“Wò ó, èmi dán wọn wo; nítorí pékí ni èmi tún le è ṣe? Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn mi?

8. Ahọ́n wọn dàbí ọfà olóróó ń sọ ẹ̀tàn; oníkálukú sì ńfi ẹnu rẹ̀ sọ̀rọ̀ àlàáfíà síaládúgbò rẹ̀; ní inúọkàn rẹ̀, ó dẹ tàkúté sílẹ̀.

9. Èmi kì yóò háa fi ìyà jẹ wọ́n nítorí èyí?”ni Olúwa wí.“Èmi kì yóò ha gbẹ̀san arami lórí irú orílẹ̀ èdè yìí bí?”

10. Èmi yóò sì sunkún, pohùnréréẹkún fún àwọn òkè; àti ẹkúnìrora lórí pápá oko ihà wọ̀n-ọn-nì.Nítorí wọ́n di ahoro, wọn kò sìkọjá ní ibẹ̀. A kò sì gbọ́ igbeẹran ọ̀sìn, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀runsì ti sá lọ, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ẹranko sì ti lọ.

Ka pipe ipin Jeremáyà 9