Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 8:12-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Ǹjẹ́ wọ́n tijú fún ìṣe ìríra wọn? Bẹ́ẹ̀ kọ́,wọn kò ní ìtìjú rárá; wọn kò tilẹ̀ mọbí wọ́n ti ṣe ń mí oru-ìtìjú. Nítorí náàwọn yóò ṣubú pẹ̀lú àwọn tó ti ṣubú,a ó sì fà wọ́n lulẹ̀ nígbà tí a bá ń fiìyà jẹ wọ́n,ni Olúwa wí.

13. “ ‘Èmi yóò mú ìkórè wọn kúròni Olúwa wí.Kì yóò sí èṣo lórí igi àjàrà,kì yóò sí ọ̀pọ̀tọ́ lórí igi, ewé wọn yóò sì rẹ̀ sílẹ̀.Ohun tí mo ti fi fún wọn ni à ó gbà kúrò.’ ”

14. “È é ṣe tí a fi jòkó ní ibí yìí?A kó ara wa jọ!Jẹ́ kí a sá lọ sí ìlú olódi kí o sì ṣègbé síbẹ̀.Nítorí tí Olúwa Ọlọ́run wa tipinnu pé a ó ṣègbé. Yóò sì fúnwa ní omi onímájèlé láti mu, nítorí àwa ti sẹ̀ sí i.

15. Àwa ń retí àlàáfíà, kò síire kan tí ó wá ní ìgbà ìmúláradábí kò ṣe ìpayà nìkan.

16. Ìró ìfọnmú ẹsin àwọn ọlọ̀tẹ̀ là ńgbọ́ láti Dánì yíyan àwọn akọ ẹsinmú gbogbo ilẹ̀ wárìrì. Wọ́n wá látipa ilẹ̀ náà run, gbogbo ohun tówà níbẹ̀, ìlú náà àti gbogbo olùgbé ibẹ̀.”

17. “Wò ó, èmi yóò rán àwọn ejò olóró síàárin yín, paramọ́lẹ̀ tí ẹ kò lè pa orówọn, yóò sì bù yín jẹ,”ni Olúwa wí.

18. Olùtùnú mi, nígbà tí ìbànújẹ́ ọkàn mirẹ̀wẹ̀sì nínú mi.

19. Fetí sí igbe àwọn ènìyàn mi láti ilẹ̀ tó jìn:“Olúwa kò ha sí ní Síóní bí?Ọba rẹ̀ kò sí níbẹ̀ mọ́ ni?”“È é ṣe tí wọ́n fi mú mi bínú pẹ̀lú ère wọn, pẹ̀lú àwọnòrìṣà àjòjì tí wọn kò ní láárí?”

20. “Ìkóórè ti ré kọ́ja, ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn ti paríṣíbẹ̀, a kò gbà wá là.”

Ka pipe ipin Jeremáyà 8