Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 8:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. “ ‘Ní ìgbà náà ni Olúwa wí pé, wọn yóò mú egungun àwọn ọba Júdà àti egungun àwọn ijoye, egungun àwọn àlùfáà àti egungun àwọn wòlíì àti egungun àwọn olùgbé Jérúsálẹ́mù kúrò nínú ibojì.

2. A ó yọ wọ́n síta fún oòrùn àti òṣùpá àti gbogbo àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run tí wọ́n ti fẹ́ràn tí wọ́n sì ti sìn, àti àwọn tí wọ́n ti tọ̀ lẹ́yìn tí wọ́n ti wá tí wọ́n sì ti foríbalẹ̀ fún. Kì yóò ṣà wọ́n jọ tàbí sìn wọ́n, wọn yóò dà bí ìdọ̀tí tó wà lórí ilẹ̀.

3. Níbikíbi tí mo bá lé wọn lọ, gbogbo àwọn ìyókù wọn yóò fẹ́ ikú ju ìyè lọ ni Olúwa Àwọn ọmọ ogun wí.’

4. “Wí fún wọn pé, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa wí:“ ‘Bí ènìyàn bá ṣubú lulẹ̀wọn kì í padà dìde bí? Nígbà tíènìyàn bá yà kúrò ní ọ̀nà rẹ,kì í yí padà bí?

5. È é ṣe nígbà náà àwọn ènìyàn wọ̀nyífi yà kúrò lọ́nà rẹ̀? Kílódé tí Jérúsálẹ́mùfi yà kúrò ní gbogbo ìgbà?Wọ́n rọ̀ mọ́ ẹ̀tàn, wọ́n kọ̀ láti yípadà.

6. Mo ti fetí sílẹ̀ dáradára, wọnkò sọ ohun tí ó tọ́. Kò sí ẹnìkan tóronúpìwàdà nínú ìwà búburú rẹ̀,kí ó wí pé, “Kí ni mo ṣe?” Olúkúlùkùń tọ ọ̀nà rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹṣin tó ń lọ sójú ogun.

Ka pipe ipin Jeremáyà 8