Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 7:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Èyí ni ọ̀rọ̀ tó tọ Jérémáyà wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa.

2. “Dúró ní ẹnu ọ̀nà ilé Olúwa kí o sì kéde ọ̀rọ̀ yí:“ ‘Ẹgbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀yin ará Júdà tí ń gba ọ̀nà yí wọlé láti wá sin Olúwa.

3. Èyi ni ọ̀rọ̀ tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí: Tún àwọn ọ̀nà yín ṣe, èmi yóò sì jẹ́ kí ẹ gbé ilẹ̀ yìí.

4. Má ṣe gba ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn gbọ́ kí ẹ sì wí pé, “Èyí ni ilé Tẹ́ḿpìlì Olúwa ilé Tẹ́ḿpìlì Olúwa, ilé Tẹ́ḿpìlì Olúwa!”

5. Bí ẹ̀yin bá tún ọ̀nà yín àti ìṣẹ́ yín ṣe nítòótọ́, tí ẹ sì ń bá ara yín lò ní ọ̀nà tó tọ́.

6. Bí ẹ kò bá fi ara ni àwọn àlejò, àwọn ọmọ aláìní baba àti àwọn opó tí ẹ kò sì ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀ ní ibí yìí, bí ẹ kò bá sì tọ Ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn sí ìpalára ara yín.

7. Nígbà náà ni èmi yóò jẹ́ kí ẹ gbé ìbí yìí, nílẹ̀ tí mo fún àwọn baba ńlá yín títí láé.

8. Ẹ wò ó, Ẹ̀ ń gba ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn tí kò níláárí gbọ́.

9. “ ‘Ẹ̀yin yóò ha jalè, kí ẹ pànìyàn, kí ẹ se pánṣágà, kí ẹ búra èké, kí ẹ sun tùràrí sí Báálì, kí ẹ sì tọ Ọlọ́run mìíràn tí ẹ̀yin kò mọ̀ lọ.

10. Nígbà náà ni kí ó wá dúró ní iwájú nínú ilé yìí tí a fi orúkọ mi pè, “Kí ẹ wá wí pé àwa yè,” sé yíyè láti ṣe gbogbo àwọn nǹkan ìnira wọ̀nyí bí?

Ka pipe ipin Jeremáyà 7