Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 6:15-30 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. Ojú há a tì wọ́n nítorí ìwàìríra wọn bí? Rárá, wọn kòní ìtìjú mọ́, wọn kò tilẹ̀ ní ooru ìtìjúNítorí náà, wọn ó ṣubú láàrinàwọn tó ṣubú, a ó sì ké wọnlulẹ̀ nígbà tí mo bá fìyà jẹ”wọ́n ni Olúwa wí.

16. Èyí ni ohun tí Olúwa wí:“Ẹ dúró sí ìkòríta, kí ẹ sì wò,ẹ bere fún ipa ìgbàanì, ẹ bèèrèọ̀nà dáradára nì, kí ẹ sì wọinú rẹ, ẹ̀yin yóò sì rí ìsinmifún ọkàn yín.Ṣùgbọ́n ẹ̀yin wí pé, ‘Àwa kì yóò rin nínú rẹ.’

17. Èmi yan olùsọ́ fún un yín,mo sì wí pé:‘Tẹ́tí sí dídún fèrè náà,’ẹ̀yìn wí pé, ‘Àwa kì yóò tẹ́tí sílẹ̀.’

18. Nítorí náà, gbọ́ ẹ̀yin orílẹ̀-èdèkíyèsí, kí ẹ sì jẹ́ ẹlẹ́rìíohun tí yóò sẹlẹ̀ sí wọn.

19. Gbọ́, ìwọ ayé! Mò ń múìparun bọ̀ sórí àwọn ènìyànwọ̀nyí, eṣo ìrò inú wọn, nítoríwọn kò fi etí sí ọ̀rọ̀ mi, wọ́n sìti kọ òfin mi sílẹ̀.

20. Èrè wo ni ó wà fún mi nínú tùràríláti ṣébà wá, tàbí eso dáradáraláti ilẹ̀ jínjìn réré? Ọrẹ sísun yínkò ṣe ìtẹ́wọ́gbà, ẹbọ yín kò sì wù mí.”

21. Nítorí náà, èyi ni ohun tí Olúwa wí:“Èmi yóò gbé ohun ìdènà ṣíwájúàwọn ènìyàn wọ̀nyí, àwọn bàbáàti ọmọ yóò jùmọ̀ ṣubú lù wọ́n,àwọn aládùúgbò àti ọ̀rẹ́ yóò ṣègbé.”

22. Èyí ni Olúwa wí:“Wò ó, àwọn ọmọ-ogun ń bọ̀ wá láti ilẹ̀ àríwá,a ó sì gbé orílẹ̀-èdè ńlá dìdeláti òpin ayé wá.

23. Wọ́n sì dìmọ́ra pẹ̀lú ọrun àti ọ̀kọ̀,Wọ́n jẹ́ ẹni ibi, wọn kò sì ní àánúwọ́n ń hó bí omi òkun, bí wọ́nti ṣe ń gun àwọn ẹsin wọn lọ;wọ́n sì wá bí ọkùnrin tí yóòjà ọ́ lógun, ìwọ ọmọbìnrin Síónì.”

24. Àwa ti gbọ́ ìròyìn nípa wọn,ọwọ́ wa sì di rírọ, ìrora sì mú wabí ìrora bí obìnrin tí í rọbí.

25. Má ṣe jáde lọ sí orí i pápátàbí kí o máa rìn ní àwọnojú ọ̀nà, nítorí ọ̀tá náà ní idà,ìpayà sì wà níbi gbogbo.

26. Ẹ̀yin ènìyàn mi, ẹ gbé asọ ọ̀fọ̀wọ̀, kí ẹ sì sùn nínú eérú, ẹsọ̀fọ̀ pẹ̀lú ìpohùnréré ẹkúngẹ́gẹ́ bí i lórí ọmọkùnrin yín, kanṣoṣonítorí pé lójijì ni àwọn apanirun yóò kọlù wá.

27. “Èmi ti fi ẹ́ ṣe ẹni tí yóò máa yọ́irú àwọn ènìyàn mi gẹ́gẹ́ bi irintútù, kí wọn kí ó lè ṣe àkíyèsí,kí ó sì dán ọ̀nà wọn wò.

28. Ọlọ́tẹ̀ tí ọkàn rẹ̀ le ní gbogbo wọn. Wọ́n ńlọ káàkiri láti sọ̀rọ̀ òdì. Wọ́n jẹ́ idẹ àti irin,wọ́n sì kún fún ìwà ìbàjẹ́.

29. Ewìrì a fẹ́ná kíkankíkán,kí ó lè yọ́ òjé,ẹni tí ń yọ́ ọ ń yọ́ ọ lásán;a ko si ya ènìyàn búburú kúrò.

30. A pè wọ́n ní fàdákà tí a kọ̀ sílẹ̀,nítorí Olúwa ti kọ̀ wọ́n sílẹ̀.”

Ka pipe ipin Jeremáyà 6