Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 51:20-30 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

20. “Ìwọ ni kùmọ̀ ohun èlò ogun mi,ohun èlò ìjà mi, pẹ̀lú rẹ èmi ó fọ́ orílẹ̀ èdè túútúú,èmi ó bà àwọn ilé Ọba jẹ́.

21. Pẹ̀lú rẹ, èmi ó pa ẹṣin àti ẹni tí ó gùn ún pẹ̀lú rẹ̀;èmi ó ba kẹ̀kẹ́ ogun jẹ́ pẹ̀lúèmi ó pa awakọ̀

22. Pẹ̀lú rẹ, mo pa ọkùnrin àti obìnrin,pẹ̀lú rẹ, mo paàgbàlagbà àti ọmọdé,Pẹ̀lú rẹ, mo pa ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin.

23. Pẹ̀lú rẹ, mo pa olùsọ́ àgùntànàti agbo àgùntàn rẹ̀;pẹ̀lú rẹ, mo pa àgbẹ̀ àti màlúù,Pẹ̀lú rẹ, mo pa gómìnà àti àwọn alákòóṣo ìjọba rẹ̀.

24. “Ní ojú rẹ, èmi yóò san án fún Bábílónì àti gbogbo àwọn olùgbé inú rẹ̀ fún gbogbo ibi tí wọ́n ti ṣe ní Síónì,”ni Olúwa wí.

25. “Mo lòdì sí ọ, ìwọ òkè apanirunìwọ ti ba gbogbo ayé jẹ́,”ni Olúwa wí.“Èmi ó na ọwọ́ mi sí ọ,èmi yóò yí ọ kúrò lórí àpáta,Èmi yóò sọ ọ́ dàbí òkè tí a ti jó.

26. A kò ní mú òkúta kankan látiọ̀dọ̀ rẹ̀ lò gẹ́gẹ́ bí igun ilé tàbífún ìpínlẹ̀ nítorí pé ìwọ yóò diahoro títí ayé,”ní Olúwa wí.

27. “Gbé àṣíá sókè ní ilẹ̀ náà, fọnipe láàrin àwọn orílẹ̀ èdè!Pèṣè àwọn orílẹ̀ èdè sílẹ̀ láti bá jagun,pe àwọn ìjọba yìí láti doju kọ ọ́,Árárátì, Mínínì àti Ásíkẹ́nì.Yan olùdarí ogun láti kọlù ú,rán àwọn ẹṣin síi bí ọ̀pọ̀ eṣú.

28. Pèsè àwọn orílẹ̀ èdè láti bá jagun,àwọn Ọba Médíà, Gómìnà àti gbogboọmọ ìgbìmọ̀ wọn àti gbogbo orílẹ̀ èdè tí wọ́n jọba lé lórí.

29. Ilẹ̀ wárìrì síhìn ín sọ́hùn ún, nítorí péète Olúwa, sí Bábílónì dúróláti ba ilẹ̀ Bábílónì jẹ́ lọ́nàtí ẹnikẹ́ni kò ní lè gbé inú rẹ̀ mọ́.

30. Gbogbo àwọn jagunjagunBábílónì tó dáwọ́ ìjà dúró la sí àgọ́ wọn.Agbára wọn ti tán, wọ́n ti dàbí obìnrin.Ibùgbé rẹ̀ ni a ti dáná sun,gbogbo irin ẹnu ọ̀nà wọn ti di fífọ́.

Ka pipe ipin Jeremáyà 51