Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 51:18-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

18. Wọn kò já mọ́ nkànkan,wọ́n jẹ́ ohun ẹlẹ́yà nígbà tí ìdájọ́ wọnbá dé, wọn ó ṣègbé.

19. Ẹni tí ó jẹ́ ìpín Jákọ́bù kó rí bí ìwọ̀nyí;nítorí òun ni ó dá ohun gbogbo,àti gbogbo àwọn ẹ̀yà ajogún, Olúwa alágbára ni orúkọ rẹ̀.

20. “Ìwọ ni kùmọ̀ ohun èlò ogun mi,ohun èlò ìjà mi, pẹ̀lú rẹ èmi ó fọ́ orílẹ̀ èdè túútúú,èmi ó bà àwọn ilé Ọba jẹ́.

21. Pẹ̀lú rẹ, èmi ó pa ẹṣin àti ẹni tí ó gùn ún pẹ̀lú rẹ̀;èmi ó ba kẹ̀kẹ́ ogun jẹ́ pẹ̀lúèmi ó pa awakọ̀

22. Pẹ̀lú rẹ, mo pa ọkùnrin àti obìnrin,pẹ̀lú rẹ, mo paàgbàlagbà àti ọmọdé,Pẹ̀lú rẹ, mo pa ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin.

23. Pẹ̀lú rẹ, mo pa olùsọ́ àgùntànàti agbo àgùntàn rẹ̀;pẹ̀lú rẹ, mo pa àgbẹ̀ àti màlúù,Pẹ̀lú rẹ, mo pa gómìnà àti àwọn alákòóṣo ìjọba rẹ̀.

24. “Ní ojú rẹ, èmi yóò san án fún Bábílónì àti gbogbo àwọn olùgbé inú rẹ̀ fún gbogbo ibi tí wọ́n ti ṣe ní Síónì,”ni Olúwa wí.

25. “Mo lòdì sí ọ, ìwọ òkè apanirunìwọ ti ba gbogbo ayé jẹ́,”ni Olúwa wí.“Èmi ó na ọwọ́ mi sí ọ,èmi yóò yí ọ kúrò lórí àpáta,Èmi yóò sọ ọ́ dàbí òkè tí a ti jó.

26. A kò ní mú òkúta kankan látiọ̀dọ̀ rẹ̀ lò gẹ́gẹ́ bí igun ilé tàbífún ìpínlẹ̀ nítorí pé ìwọ yóò diahoro títí ayé,”ní Olúwa wí.

27. “Gbé àṣíá sókè ní ilẹ̀ náà, fọnipe láàrin àwọn orílẹ̀ èdè!Pèṣè àwọn orílẹ̀ èdè sílẹ̀ láti bá jagun,pe àwọn ìjọba yìí láti doju kọ ọ́,Árárátì, Mínínì àti Ásíkẹ́nì.Yan olùdarí ogun láti kọlù ú,rán àwọn ẹṣin síi bí ọ̀pọ̀ eṣú.

Ka pipe ipin Jeremáyà 51