Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 50:30-44 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

30. Nítorí náà, àwọn ọmọkùnrin rẹ̀yóò ṣubú ní ìgboro, a ó sì pa àwọnológun lẹ́nu mọ́,”ní Olúwa wí.

31. “Wò ó, èmi lòdì sí àwọn onígbéraga,”ni Olúwa Ọlọ́run,“ọmọ ogun wí, nítorí ọjọ́ rẹti dé tí ìwọ yóò jìyà.

32. Onígbéraga yóò kọsẹ̀, yóòsì ṣubú, kì yóò sì sí ẹni tí yóò gbé dìde.Èmi yóò tan iná ní ìlú náà,èyí tí yóò sì jo run.”

33. Èyí ni ohun tí Olúwa alágbára sọ:“A pọ́n àwọn ènìyàn Ísírẹ́lìlójú àti àwọn ènìyàn Júdà pẹ̀lú.Gbogbo àwọn tí ó kó wọnnígbèkùn dì í mú ṣinṣinwọn kò sì jẹ́ kí ó sá àsálá.

34. Síbẹ̀, Olùràpadà wọn, Alágbára, Olúwa Ọlọ́run alágbára ni orúkọ rẹ̀.Yóò sì gbe ìjà wa jà,kí ó ba à lè mú wọn wá sinmí ní ilẹ̀ náà;àmọ́ kò sí ìsinmi fún àwọn tí ó ń gbé Bábílónì.

35. “Idà lórí àwọn Bábílónì!”ni Olúwa wí,“lòdì sí àwọn tó ń gbé ní Bábílónì,àwọn aláṣẹ àti àwọn amòye ọkùnrin.

36. Idà lórí àwọn wòlíì èkéwọn yóò di òmùgọ̀! Idà lórí àwọn jagunjagun,wọn yóò sì kún fún ẹ̀rù.

37. Idà lórí àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀àti àwọn àjòjì nínú ẹgbẹ́ rẹ̀.Wọn yóò di obìnrin.Idà lórí àwọn ohun ìṣura rẹ̀!

38. Ilẹ̀ gbígbẹ lórí omi rẹ̀; yóò sì gbẹ.Nítorí pé ó jẹ́ ilẹ̀ àwọn ère,àwọn ère tí yóò ya òmùgọ̀ pẹ̀lú ẹ̀rù.

39. “Nítorí náà àwọn ẹranko ijùpẹ̀lu ọ̀wàwà ni yóò máa gbé ibẹ̀,abo ògòǹgò yóò sì máa gbé inú rẹ̀,a kì ó sì gbé inú rẹ̀ mọ́, láéláé,bẹ́ẹ̀ ni a kì ó ṣàtìpó nínú rẹ̀ láti ìrandíran.

40. Gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti gba ìjọbaSódómù àti Gòmóràpẹ̀lú àwọn ìlú agbégbé wọn,”ni Olúwa wí,“kì yóò sí ẹni tí yóò gbé ibẹ̀.

41. “Wò ó! Ọ̀wọ́ ọmọ ogun láti ìhà àríwá;orílẹ̀ èdè ńlá àti àwọn Ọba pípọ̀ ni à ńgbé dìde láti òpin ilẹ̀ ayé.

42. Wọ́n sì di ìhámọ́ra ọ̀kọ̀ àti ọrun,wọ́n burú wọn kò sì ní àánú.Wọ́n bú bí i rírú omi bí wọ́n ti se ń gun ẹsin wọn lọ.Wọ́n wá bí àkójọpọ̀ ogun láti kọlù ọ́, ìwọ ọmọbìnrin Bábílónì.

43. Ọba Bábílónì ti gbọ́ ìròyìn nípa wọn,ọwọ́ wọn sì rọ,ìrora mú wọn bí obìnrin tí ó ń rọbí.

44. Bí i kìnnìún tí ń bú láti igbó Jọ́dánì.N ó lé Bábílónì kúrò ní ilẹ̀ rẹ̀ ní kánmọ́ kánmọ́.Ta ni ẹni àyànfẹ́ náà tí n ó yàn?Ta ló dàbí mi, ta ló dàbí mi,ta ló sì le dojú ìjà kọmí?”

Ka pipe ipin Jeremáyà 50