Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 50:13-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

13. Nítorí ìbínú Olúwa, kì yóò ní olùgbé;ẹnikẹ́ni kò sì ní gbé inú rẹ̀.Gbogbo àwọn tí ó bá kọjá ni Bábílónì yóòfi ṣe yẹ̀yẹ́ nítorí ọgbẹ́ rẹ̀.

14. “Dúró sí àyè rẹ ìwọ Bábílónìàti gbogbo ẹ̀yin tí ẹ ta ọfà náà.Ẹ ta ọfà náà síi, nítorí ó ti sẹ̀ sí Olúwa.

15. Kígbe mọ-ọn ní gbogbo ọ̀nà!Ó tẹríba, òpó rẹ̀ sì yẹ̀,níwọ̀n ìgbà tí ó ti jẹ́ wí pé èyí ni ìgbẹ̀san Olúwa,gbẹ̀san lára rẹ̀.Ṣe síi gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe sí àwọn ẹlòmìíràn.

16. Mú kúrò ní Bábílónì olùgbìnàti olùkórè pẹ̀lú ohun ìkórè rẹ̀.Nítorí idà àwọn aninilárajẹ́ kí oníkálùkù padà sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀,kí oníkálukú sì sá padà sí ilẹ̀ rẹ̀.

17. “A ti fọ́n Ísírẹ́lì ká, Kìnnìún sì ti lé e lọ.Ẹni àkọ́kọ́ tí ó kọ́kọ́ jẹ ẹ́ ni Ọba Ásíríà,ẹni tí ó sì jẹ eegun rẹ̀kẹ́yìn ni Nebukadinésárì Ọba Bábílónì.”

18. Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run alágbára Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí;“Ǹ ó fi ìyà jẹ Ọba Bábílónì àti ilẹ̀ rẹ̀gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe fìyà jẹ Ọba, Ásíríà.

19. Ṣùgbọ́n, èmi yóò mú Ísírẹ́lìpadà wá pápá oko tútù rẹ̀òun yóò sì máa bọ́ ara rẹ̀ lórí kámẹ̀lì àti Básánì,a ó sì tẹ́ ọkàn rẹ̀ lọ́rùn ní òkèÉfúráímù àti ní Gílíádì

Ka pipe ipin Jeremáyà 50