Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 5:22-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

22. Kò ha yẹ kí ẹ bẹ̀rù mi?” ni Olúwa wí.“Kò ha yẹ kí èyin ó wárìrì níwájú mi bí?Mo fi yanrìn pààlà òkun,èyí tí kò le è rékọjá rẹ̀ láéláé.Ìjì lè jà, kò le è borí rẹ̀;wọ́n le è bú, wọn kò le è rékọjá rẹ̀.

23. Ṣùgbọ́n, àwọn ènìyàn wọ̀nyí ní ọkàn líle àti ọkàn ọ̀tẹ̀,wọ́n ti yípadà, wọ́n sì ti lọ.

24. Wọn kò sọ fún ara wọn pé,‘Ẹ jẹ́ ká a bẹ̀rù Olúwa Ọlọ́run wa,ẹni tí ó fún wa ní òjò àkọ́rọ̀ àti àrọ̀kúrò òjò ní ìgbà rẹ̀,tí ó fi wá lọ́kàn balẹ̀ nípa ìkórè ọ̀sẹ̀ déédéé.’

25. Àìṣedéedée yín mú gbogbo nǹkan wọ̀nyí kúrò,ẹ̀ṣẹ̀ yín sì mú kí a fi nǹkan rere dù yín.

26. “Láàrin ènìyàn mi ni ìkà ènìyàn wàtí ó wà ní ibùba bí ẹni tí ó ń dẹ ẹyẹ,àti bí àwọn tí ó ń dẹ pàkúté láti mú ènìyàn.

27. Bí àgò tí ó kún fún ẹyẹ,ilé wọn sì kún fún ẹ̀tàn.Wọ́n ti di ọlọ́lá àti alágbára,

28. Wọ́n sanra wọ́n sì dán.Ìwà búburú wọn kò sì lópin;wọn kò bẹ̀bẹ̀ fún ẹjọ́ àwọn aláìní baba láti borí rẹ̀.Wọn kò jà fún ẹ̀tọ́ àwọn tálákà.

29. Èmi kì yóò ha fi ìyà jẹ wọ́n fún èyí bí?”ni Olúwa wí.“Èmi kì yóò wá gbẹ̀san ara milára orílẹ̀ èdè bí èyí bí?

30. “Nǹkan ìbànújẹ́ àti ohun ìtarati ṣẹlẹ̀ ní ilẹ̀ náà.

31. Àwọn wòlíì ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké,àwọn àlùfáà sì ń ṣe àkóso pẹ̀lú àṣẹ ara wọn,àwọn ènìyàn mi sì nífẹ̀ẹ́ sí èyí,kí ni ẹ̀yin yóò ṣe ní òpin?

Ka pipe ipin Jeremáyà 5