Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 46:20-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

20. “Ẹgbọ̀rọ̀ abo màlúù tó lẹ́wà ní Éjíbítìṣùgbọ́n eṣinṣintí yóò le ń bọ̀ láti àríwá.

21. Àwọn jagunjagun rẹ̀dàbí àbọ́pa màlúù.Àwọn pẹ̀lú yóò yípadà,wọn ó sì jùmọ̀ sá,wọn kò ní le dúró,Nítorí tí ọjọ́ ibi ńbọ̀ lórí wọnàsìkò láti jẹ wọ́n níyà.

22. Éjíbítì yóò pòṣé bí ejò tí ń sábí ọmọ ogun ṣe ń tọ̀ ọ́ wá pẹ̀lú agbára.Wọn ó tọ̀ ọ́ wá pẹ̀lú àáké,gẹ́gẹ́ bí i ti agégi.

23. Wọn o gé igbó rẹ̀ lulẹ̀,”ni Olúwa wí,“nítorí ti a kò le rídìí rẹ̀,nítorí pé wọ́n pọ̀ ju elẹ́ǹgà lọ, wọ́n sì jẹ́ àìníye.

24. A ó dójú ti ọmọbìnrin Éjíbítì,a ó fà á lé ọwọ́ àwọn ènìyàn àríwá.”

25. Olúwa àwọn ọmọ-ogun jùlọ, Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí pé: “Èmi ṣetán láti fi ìyà jẹ Ámónì, òrìṣà Tíbísì, Fáráò Éjíbítì àti àwọn òrìṣà rẹ̀ àti àwọn Ọba rẹ̀ àti àwọn tó gbẹ́kẹ̀lé Fáráò.

26. Èmi ó sì fi wọ́n lé àwọn tó wá ẹ̀mí wọn lọ́wọ́, lé Nebukadinésárì Ọba Bábílónì, ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, Éjíbítì yóò sì di gbígbé bí i ti àtijọ́,” ni Olúwa wí.

27. “Má bẹ̀rù, ìwọ Jákọ́bù ìránṣẹ́ mi,má fòyà, ìwọ Ísírẹ́lì.Dájúdájú èmi ó gbà ọ́ láti ọ̀nà jínjìn,àwọn ọmọ ọmọ rẹ ní ilẹ̀ ìgbèkùn.Jákọ́bù yóò tún ní àlàáfíà àti ààbò,kò sì sí ẹni tí yóò dẹ́rù bà á.

28. Má bẹ̀rù, Jákọ́bù ìránṣẹ́ mi,nítorí pé mo wà pẹ̀lú rẹ,” bẹ́ẹ̀ ni Olúwa wí.“Bí mo tilẹ̀ pa gbogbo orílẹ̀ èdè run,láàrin àwọn tí mo fọ́n yín ká sí.Èmi kò ní run yín tán.Èmi yóò jẹ ọ́ níyà lórí òdodo,èmi kò ní fi ọ́ sílẹ̀ láìjẹ ọ́ níyà.”

Ka pipe ipin Jeremáyà 46