Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 44:5-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Ṣùgbọ́n wọn kò fetísílẹ̀ láti fi ọkàn si. Wọn kò sì yípadà kúrò nínú búburú wọn tàbí dáwọ́ ẹbọ sísun sí àwọn òrìṣà dúró.

6. Fún ìdí èyí, ìbínú gbígbóná mi ni èmi yóò yọ sí àwọn ìlú Júdà àti òpópó Jérúsálẹ́mù àti sísọ wọ́n di ìparun bí ó ṣe wà lónìí yìí.

7. “Báyìí tún ni Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì wí: Kí ló dé tí ẹ fi ń mu ibi ńlá yìí wá sí orí ara yín nípa yíyapa kúrò lára Júdà ọkùnrin àti obìnrin, ọmọdé àti èwe, tí ẹ kò sì ku ọ̀kankan?

8. Èéṣe tí ẹ fi mú mi bínú pẹ̀lu ohun tí ọwọ́ yín ṣe pẹ̀lú ẹbọ sísun sí àwọn òrìṣà Éjíbítì, níbi tí ẹ wá láti máa gbé? Ẹ̀ ò pa ara yín run, ẹ̀ ó sì sọ ara yín di ẹni ìfiré àti ẹ̀gàn láàrin àwọn orílẹ̀ èdè ayé gbogbo.

9. Ṣé ẹ̀yin ti gbàgbé ibi tí àwọn bàbá ńlá yín àti àwọn Ọba; àwọn ayaba Júdà, àti àwọn ibi tí ẹ ti ṣe àti àwọn ìyàwó yín ní ilẹ̀ Júdà àti ní òpópó Jérúsálẹ́mù?

10. Láti ìgbà náà sí àkókò yìí, wọn kò rẹ ara wọn sílẹ̀ tàbí fi ìtẹ́ríba hàn tàbí kí wọn ó tẹ̀lé òfin àti àṣẹ tí mo pa fún un yín àti àwọn baba yín.

11. “Fún ìdí èyí, báyìí ni Olúwa Ọlọ́run àwọn Ísírẹ́lì wí: Mo ti pinnu láti mú ibi wá sí orí yín àti láti pa Júdà run.

Ka pipe ipin Jeremáyà 44