Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 4:29-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

29. Nípa ariwo àwọn ẹlẹ́ṣin àti àwọn tafàtafàgbogbo ìlú yóò sálọ.Ọ̀pọ̀ sálọ sínú igbó;ọ̀pọ̀ yóò sì gun orí àpáta lọ.Gbogbo ìlú náà sì di ahoro;kò sì sí ẹnìkan nínú rẹ̀.

30. Kí ni ò ń ṣe, ìwọ tí o ti di ìjẹ tán?Ìwọ ìbá wọ ara rẹ ní aṣọ òdodokí o sì fi wúrà ṣe ara rẹ lọ́ṣọ̀ọ́.Àwọn olólùfẹ́ rẹ kẹ́gàn rẹwọ́n sì ń lépa ẹ̀mí rẹ.

31. Mo gbọ́ ìró kan bí i igbe obìnrin tó ń rọbí,tí ó ń rọbí, ìrora bí i abiyamọọmọbìnrin Síónì tí ń pohùnréré ẹkún ara rẹ̀.Tí ó na ọwọ́ rẹ̀ tí ó sì wí pé,“Kíyèsí i mo gbé,Nítorí a ti fi ẹ̀mí mi lé àwọn apani lọ́wọ́.”

Ka pipe ipin Jeremáyà 4