Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 4:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. “Tí ìwọ yóò bá padà, Ìwọ Ísírẹ́lìpadà tọ̀ mí wá,”ni Olúwa wí.“Tí ìwọ yóò bá sì mú àwọn òrìṣà tí ìwọ ń ṣe kúrò níwájú mi,tí o kò sì yapa,

2. Tí ó bá jẹ́ lóòtọ́ àti òdodo niìwọ búra. Nítòótọ́ bí Olúwa ti wà láàyè,nígbà náà ni orílẹ̀ èdè yóò di alábùkún fúnnípaṣẹ̀ rẹ àti nínú rẹ̀ ni wọn yóò ṣògo.

3. Èyí ni ohun tí Olúwa wí fún àwọn ènìyàn Júdà àti Jérúsálẹ́mù.“Hú gbogbo ilẹ̀ tí ẹ kò lò rí,kí o má sì ṣe gbìn sáàrín ẹ̀gún.”

4. Kọ ara rẹ ní ilà sí Olúwakọ ọkàn rẹ ní ilàẹ̀yin ènìyàn Júdà àti gbogbo ènìyàn Jérúsálẹ́mù,bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ìbínú mi yóò ru jáde yóò sì jó bí iná,nítorí ibi tí o ti ṣekì yóò sí ẹni tí yóò pa á.

5. “Kéde ní Júdà, kí o sì polongo ní Jérúsálẹ́mù, kí o sì wí pé:‘fun fèrè káàkiri gbogbo ilẹ̀. Kí o sì kígbe,‘kó ara jọ pọ̀!Jẹ́ kí a sálọ sí ìlú olódi.’

6. Fi àmì láti sálọ sí Síónì hàn,sálọ fún ààbò láìsí ìdádúró.Nítorí èmi ó mú àjálù láti àríwá wá,àní ìparun tí ó burú jọjọ.”

7. Kìnnìún ti sá jáde láti inú ibùgbé rẹ̀,apanirun orílẹ̀ èdè sì ti jáde.Ó ti fi àyè rẹ̀ sílẹ̀láti ba ilẹ̀ rẹ̀ jẹ́.Ìlú rẹ yóò di ahoroláìsí olùgbé.

8. Nítorí náà, gbé aṣọ ọ̀fọ̀ wọ̀káàánú, kí o sì pohùnréré ẹkún,nítorí ìbínú ńlá Olúwakò tí ì kúrò lórí wa.

9. “Ní ọjọ́ náà,” ni Olúwa wí pé,“àwọn Ọba àti ìjòyè yóò pàdánù ẹ̀mí wọn,àwọn àlùfáà yóò wárìrì,àwọn wòlíì yóò sì fòyà.”

10. Nígbà náà ni mo sì wí pé, “Áà! Olúwa àwọn ọmọ-ogun, báwo ni ìwọ ti ṣe tan àwọn ènìyàn wọ̀nyí àti Jérúsálẹ́mù jẹ nípa sísọ wí pé, ‘Ìwọ yóò wà ní àlàáfíà,’ nígbà tí o fẹ́ wí pé idà wà ní ọ̀fun wa.”

Ka pipe ipin Jeremáyà 4