Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 39:4-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Nígbà tí Sedekáyà Ọba Júdà àti àwọn ọmọ ogun rí wọn, wọ́n sá, wọ́n kúrò ní ìlú ní alẹ́, wọ́n gba ọ̀nà ọgbà Ọba lọ láàrin ẹnubodè pẹ̀lú odi méjì, wọ́n dojúkọ aginjù.

5. Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn ọmọ ogun Bábílónì lé wọn, wọ́n bá Sedekáyà láàrin ihà Jẹ́ríkò. Wọ́n mú un ní ìgbékùn, wọ́n sì mú u tọ Nebukadinésárì Ọba Bábílónì àti Rábílà ní ilẹ̀ Hámátì, níbi tí wọ́n ti ṣe ìdájọ́ rẹ̀.

6. Níbẹ̀ ní Rábílà, ni Ọba Bábílónì ti dúńbú àwọn ọmọ Sedekáyà lójú rẹ̀, tí ó sì tún pa gbogbo àwọn ọlọ́lá ilẹ̀ Júdà.

7. Nígbà náà ni ó fọ́ ojú Sedekáyà, ó sì dè é pẹ̀lú ẹ̀wọ̀n láti gbé e lọ sí ilẹ̀ Bábílónì.

8. Àwọn Bábílónì dáná sun ààfin Ọba àti ilé àwọn ènìyàn, wọ́n sì wó odi Jérúsálẹ́mù.

9. Nebukadinésárì olórí àwọn ọmọ ogun mú lọ sí ìgbékùn Bábílónì pẹ̀lú gbogbo àwọn tí ó ṣẹ́kù nínú ìlú.

10. Ṣùgbọ́n Nebukadinésárì olórí ogun fi àwọn aláìní sílẹ̀ ní Júdà, àwọn tí kò ní ohun kankan ní àkókò náà, ó fún wọn ní ọgbà àjàrà àti oko.

11. Nísinsìnyìí, Nebukadinésárì Ọba àwọn Bábílónì pàṣẹ lórí Jeremáyà, láti ọ̀dọ̀ Nebusárádánì olórí ogun wá wí pé:

12. “Ẹ gbé e, kí ẹ sì bojú tó o. Ẹ má ṣe ṣe ohun búburú fún un, ṣùgbọ́n ohunkóhun tó bá béèrè ni kí ẹ fi fún un.”

13. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ pẹ̀lú, Nebusárádánì olùdarí ọmọ ogun, Nebusasibánì, olóyè àgbà, Nágálì Sárésà, olóyè àgbà àti gbogbo àwọn olóyè ọba,

14. ránṣẹ́ láti mú Jeremáyà kúrò nínú túbú. Wọ́n gbé e lọ fún Jedalíyà ọmọ Álúkámù ọmọ Sápámù láti mú padà lọ sí ilé àti máa wà pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀.

15. Nígbà tí Jeremáyà wà nínú túbú, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ ọ́ wá wí pé:

16. “Lọ sọ fún Ebedimélékì ará Kúṣì, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí: Èmi ṣetan láti mú ọ̀rọ̀ mi ṣẹ lórí ìlú yìí nípa àjálù kì í ṣe àlàáfíà. Ní àkókò náà ni yóò ṣẹ lójú rẹ.

Ka pipe ipin Jeremáyà 39